-
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tí Ọlọ́run Fẹ́ràn‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
2 Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Ohun tí òwe yìí sọ kọjá wíwulẹ̀ mọ ẹnì kan lóréfèé. Gbólóhùn náà ‘ń bá rìn’ túmọ̀ sí àjọṣe tó ń bá a nìṣó.a Nígbà tí ìwé kan tó dá lórí Bíbélì, èyí tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ máa sọ ọ́, ó ní: “Bíbá ẹnì kan rìn fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ onítọ̀hún, àti pé àjọṣe kan wà láàárín wa.” Àbí ìwọ náà ò mọ̀ pé a máa ń fẹ́ fara wé àwọn tá a bá fẹ́ràn? Ká sòótọ́, torí pé ọ̀dọ̀ àwọn tá a fẹ́ràn lọkàn wa máa ń wà lọ́pọ̀ ìgbà, ipa kékeré kọ́ ni wọ́n máa ń ní lórí wa, yálà sí rere tàbí búburú.
-
-
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tí Ọlọ́run Fẹ́ràn‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
a Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “ní ìbálò pẹ̀lú” làwọn kan tún túmọ̀ sí “bá kẹ́gbẹ́” àti ‘bá rìn.’—Àwọn Onídàájọ́ 14:20; Òwe 22:24, Bibeli Ajuwe.
-