-
Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì NìṣóGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 12
Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Nìṣó
Èrè púpọ̀ wà nínú kéèyàn máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o dá ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́ dúró. Kí nìdí tó fi yẹ kó o sapá láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó? Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí ẹ̀kọ́ náà ò fi ní sú ẹ?
1. Àǹfààní wo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ṣe ẹ́?
“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára.” (Hébérù 4:12) Bíbélì ń ṣeni láǹfààní gan-an torí ó jẹ́ ká mọ èrò Ọlọ́run àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Yàtọ̀ sí pé Bíbélì máa jẹ́ kó o ní ìmọ̀, ó tún máa jẹ́ kó o ní ọgbọ́n tòótọ́ àti ìrètí. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Bíbélì máa jẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa nípa rere lórí ìgbésí ayé rẹ.
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká mọ àǹfààní tí ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ṣe wá?
Àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì dà bí ìṣúra iyebíye. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rọ̀ wá pé ká ‘ra òtítọ́, ká má sì tà á láé.’ (Òwe 23:23) Tá a bá ń fi sọ́kàn pé ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ṣe wá láǹfààní púpọ̀, àá máa ṣiṣẹ́ kára láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó kódà tí ohunkóhun bá fẹ́ dí wa lọ́wọ́.—Ka Òwe 2:4, 5.
3. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó?
Jèhófà fẹ́ kó o mọ òun torí òun ni Ẹlẹ́dàá rẹ atóbilọ́lá àti Ọ̀rẹ́ rẹ. Ó lè ‘mú kó wù ẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀, kó sì fún ẹ ní agbára láti ṣe é.’ (Ka Fílípì 2:13.) Torí náà, tí ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́ bá fẹ́ sú ẹ tàbí tí kò rọrùn fún ẹ láti fi àwọn ohun tó ò ń kọ́ sílò, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tí ohunkóhun bá ń dí ẹ lọ́wọ́ tàbí tí àwọn kan ń ta kò ẹ́, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Máa gbàdúrà déédéé sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó.—1 Tẹsalóníkà 5:17.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kọ́ bó o ṣe lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ta kò ẹ́ tàbí tó o bá ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe. Wàá sì tún kọ́ bí Jèhófà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó.
4. Fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́
Nígbà míì ọwọ́ wa máa ń dí gan-an, táá sì máa ṣe wá bíi pé a ò lè ráyè láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́? Ka Fílípì 1:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Lérò tìẹ, kí ni “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” nígbèésí ayé ẹni?
Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́ ṣe pàtàkì sí ẹ?
Tó o bá kọ́kọ́ da iyanrìn sínú ike kan kó o tó kó òkúta sínú ẹ̀, àyè ò ní gba àwọn òkúta yẹn
Tó o bá kọ́kọ́ kó òkúta sínú ike náà, wàá rí àyè tó o máa da èyí tó pọ̀ jù nínú iyanrìn náà sí. Bákan náà ló rí tó o bá fi “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ, wàá lè ṣe wọ́n láṣeyọrí, wàá sì tún rí àyè láti ṣe àwọn nǹkan míì
Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á jẹ́ kó o mọ Ọlọ́run, kó o sún mọ́ ọn, kó o sì máa jọ́sìn rẹ̀. Ka Mátíù 5:3, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ Bíbélì?
5. Máa fara dà á tí wọ́n bá ń ta kò ẹ́
Ó lè ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan ò ní fẹ́ kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wo àpẹẹrẹ Francesco. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, kí làwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé Francesco ṣe nígbà tó sọ ohun tó ń kọ́ fún wọn?
Báwo ni Ọlọ́run ṣe san èrè fún Francesco torí pé kò jáwọ́ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Ka 2 Tímótì 2:24, 25, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé inú ìdílé rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ dùn sí ohun tó ò ń kọ́?
Bí àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣe sọ, kí ló yẹ kó o ṣe táwọn kan bá ń ṣe ohun tí kò dáa sí ẹ torí pé ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Kí nìdí tí wàá fi ṣe bẹ́ẹ̀?
6. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́
Bá a bá ṣe ń sún mọ́ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ lá máa wù wá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Síbẹ̀, ó lè nira fún wa láti ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé wa tó máa bá ìlànà rẹ̀ mu. Tó bá nira fún ẹ, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, àwọn àyípadà wo ni Jim ṣe kó lè ṣe ìfẹ́ Jèhófà?
Kí ló wú ẹ lórí nínú ohun tó ṣe?
Ka Hébérù 11:6, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ni Jèhófà máa ṣe fún àwọn “tó ń wá a tọkàntọkàn,” ìyẹn àwọn tó ń sapá gan-an láti mọ̀ ọ́n kí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀?
Báwo lo ṣe rò pé ó máa ń rí lára Jèhófà bó ṣe ń rí gbogbo akitiyan rẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó?
ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí nìdí tó o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?”
Kí lo máa sọ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í rọrùn nígbà gbogbo láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kó o lè gbádùn ayé rẹ títí láé. Ṣáà máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa san ẹ́ lérè.
Kí lo rí kọ́?
Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ Bíbélì fi ṣeyebíye sí ẹ?
Báwo lo ṣe lè “máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù”?
Kí nìdí tó fi yẹ kó o bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo ohun mẹ́rin tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ tí wọ́n fi ń lo àkókò wọn lọ́nà tó dáa.
“Bó O Ṣe Lè Máa Lo Àkókò Rẹ Lọ́nà Tó Dáa” (Jí!, February 2014)
Wo bí Jèhófà ṣe ran obìnrin kan lọ́wọ́ tí ọkọ rẹ̀ ò kọ́kọ́ mọ ìdí tó fi ń sapá láti sin Ọlọ́run.
Wo bí ọkùnrin kan ṣe jàǹfààní torí pé ìyàwó rẹ̀ fara da àtakò.
Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń fẹ̀sùn kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé à ń tú ìdílé ká. Àmọ́, ṣé òótọ́ ni?
-
-
Bá A Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó DáaGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 35
Bá A Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Dáa
Gbogbo wa la máa ń ṣe ìpinnu. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìpinnu tá à ń ṣe lè ṣe wá láǹfààní tàbí kó ṣàkóbá fún wa. Bákan náà, wọ́n lè mú ká sún mọ́ Jèhófà tàbí ká jìnnà sí i. Lára àwọn ìpinnu tá a máa ń ṣe ni ibi tá a máa gbé, iṣẹ́ tá a máa ṣe, tàbí bóyá a máa ní ọkọ tàbí ìyàwó. Tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó dáa, ayé wa máa dùn, àá sì máa ṣohun tó máa múnú Jèhófà dùn.
1. Báwo lo ṣe lè lo Bíbélì láti ṣe ìpinnu tó dáa?
Kó o tó ṣàwọn ìpinnu pàtàkì, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ náà. (Ka Òwe 2:3-6.) Nígbà míì, o lè ráwọn ibi tí Jèhófà ti pàṣẹ nínú Bíbélì pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan tàbí pé ohun báyìí ni ká ṣe. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun tó dáa jù ni pé kó o tẹ̀ lé àwọn àṣẹ yẹn.
Àmọ́, kí ló yẹ kó o ṣe tí Bíbélì ò bá sọ ohun tó yẹ ká ṣe ní pàtó? Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀, ó ṣì máa jẹ́ kó o mọ “ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.” (Àìsáyà 48:17) Báwo ló ṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn ìlànà tó lè tọ́ ẹ sọ́nà wà nínú Bíbélì. Àwọn ìlànà Bíbélì ni òótọ́ ọ̀rọ̀ tó ń jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan. Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá ka ìtàn kan nínú Bíbélì, ó máa jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan. Tá a bá sì mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, èyí á jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó máa múnú rẹ̀ dùn.
2. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o fi sọ́kàn kó o tó ṣèpinnu?
Bíbélì sọ pé: “Aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.” (Òwe 14:15) Torí náà, ká tó ṣèpinnu, ó yẹ ká fara balẹ̀ dáadáa, ká sì ronú jinlẹ̀ nípa ohun tá a fẹ́ ṣe. Bó o ṣe ń ronú nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpinnu tó o fẹ́ ṣe, bi ara ẹ pé: ‘Ìlànà Bíbélì wo ló sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí? Ìpinnu wo ni mo lè ṣe tó máa jẹ́ kí n ní àlàáfíà, kí ọkàn mi sì balẹ̀? Ṣé ìpinnu tí mo fẹ́ ṣe yìí ò ní kó bá àwọn ẹlòmíì? Ìbéèrè tó wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ṣé ìpinnu yìí á múnú Jèhófà dùn?’—Diutarónómì 32:29.
Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tí kò yẹ ká ṣe. Tá a bá mọ àwọn òfin àtàwọn ìlànà rẹ̀ dáadáa, tá a sì pinnu pé àá máa tẹ̀ lé wọn, ẹ̀rí ọkàn wa á máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Ẹ̀rí ọkàn ni ohun tí Jèhófà dá mọ́ wa, tó máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó dáa àtohun tí kò dáa. (Róòmù 2:14, 15) Tá a bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa dáadáa, á jẹ́ ká máa ṣàwọn ìpinnu tó dáa.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká túbọ̀ wo bí àwọn ìlànà Bíbélì àti ẹ̀rí ọkàn wa ṣe lè mú ká máa ṣe ìpinnu tó dáa.
3. Jẹ́ kí Bíbélì máa tọ́ ẹ sọ́nà
Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè tọ́ wa sọ́nà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Òmìnira wo ni Jèhófà fún gbogbo wa?
Kí nìdí tí Jèhófà fi fún wa lómìnira láti yan ohun tó wù wá?
Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà fún wa tó máa jẹ́ ká lo òmìnira wa lọ́nà tó dáa jù lọ?
Kó o lè rí àpẹẹrẹ ìlànà Bíbélì kan, ka Éfésù 5:15, 16. Lẹ́yìn náà, sọ bó o ṣe lè ‘lo àkókò ẹ lọ́nà tó dára jù lọ’ kó o lè . . .
máa ka Bíbélì lójoojúmọ́.
jẹ́ ọkọ, aya, òbí tàbí ọmọ rere.
máa lọ sáwọn ìpàdé ìjọ.
4. Kọ́ ẹ̀rí ọkàn ẹ kó lè máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó dáa
Tí òfin pàtó bá wà nínú Bíbélì nípa ohun tó yẹ ká ṣe tàbí ohun tá ò gbọ́dọ̀ ṣe, ó sábà máa ń rọrùn láti mọ ohun tó yẹ ká ṣe. Àmọ́, kí la máa ṣe tí kò bá sírú àwọn òfin bẹ́ẹ̀? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, báwo ni arábìnrin yẹn ṣe kọ́ ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ kó lè ràn án lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ káwọn míì bá wa ṣe ìpinnu tó yẹ káwa fúnra wa ṣe? Ka Hébérù 5:14, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ló yẹ kí àwa fúnra wa lè fi ìyàtọ̀ sí táwọn ẹlòmíì bá tiẹ̀ lè bá wa ṣèpinnu?
Àwọn nǹkan wo ni ètò Ọlọ́run ti ṣe fún wa tó lè jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa, ká sì lè ṣàwọn ìpinnu tó dáa?
Bí àwòrán tó ń júwe ọ̀nà ṣe máa ń jẹ́ kéèyàn mọ ibi tó ń lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe máa ń tọ́ wa sọ́nà
5. Bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì
Ìpinnu wa máa ń yàtọ̀ síra. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì yìí:
Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́: Arábìnrin kan fẹ́ràn kó máa tọ́jú tọ́tè. Àmọ́, ó wá kó lọ sí àdúgbò míì táwọn ará ò ti gbà pé ó bójú mu kéèyàn máa tọ́jú tọ́tè.
Ka Róòmù 15:1 àti 1 Kọ́ríńtì 10:23, 24, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Pẹ̀lú ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, kí ni arábìnrin yẹn lè ṣe? Ká sọ pé o fẹ́ ṣe ohun kan tí kò da ẹ̀rí ọkàn ẹ láàmú, àmọ́ tó ń da ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíì láàmú, kí ni wàá ṣe?
Àpẹẹrẹ kejì: Arákùnrin kan mọ̀ pé Bíbélì ò sọ pé kéèyàn má mu ọtí, tó bá ṣáà ti jẹ́ níwọ̀nba. Àmọ́ arákùnrin yìí ti pinnu pé òun ò ní máa mu ọtí. Wọ́n wá pè é síbi àpèjẹ kan tí àwọn ará ti ń mu ọtí.
Ka Oníwàásù 7:16 àti Róòmù 14:1, 10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Pẹ̀lú ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, kí ni kò yẹ kí arákùnrin yẹn ṣe? Kí lo máa ṣe tó o bá rí i pé ẹnì kan ń ṣe ohun kan tí kò bá ẹ̀rí ọkàn tìẹ mu?
Bó o ṣe lè ṣe ìpinnu tó dáa
1. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe.—Jémíìsì 1:5.
2. Ṣe ìwádìí nínú Bíbélì àtàwọn ìwé àti fídíò tó ń ṣàlàyé Bíbélì. O tún lè fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn.
3. Máa ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ tó o bá ń ṣèpinnu. Ronú nípa àkóbá tó lè ṣe fún ẹ, kó o sì wò ó bóyá kò ní da ẹ̀rí ọkàn àwọn míì láàmú.
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ohun tó bá wù mi ni mo lè ṣe. Kò sóhun tó kàn mí pẹ̀lú bó ṣe rí lára àwọn ẹlòmíì.”
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan àti bó ṣe máa rí lára àwọn míì?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó dáa, a gbọ́dọ̀ máa ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, ká sì wò ó bóyá ohun tá a fẹ́ ṣe yẹn máa ṣe àwọn míì láǹfààní àbí ó máa ṣàkóbá fún wọn.
Kí lo rí kọ́?
Báwo lo ṣe lè ṣe ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn?
Báwo lo ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ?
Báwo lo ṣe lè máa fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn àwọn míì?
ṢÈWÁDÌÍ
Báwo lo ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?
“Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga” (Ilé Ìṣọ́, April 15, 2011)
Wo fídíò yìí kó o lè túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe máa ń fún wa ní ìmọ̀ràn.
Wo fídíò yìí kó o lè rí ohun tó ran ọkùnrin kan lọ́wọ́ nígbà tó fẹ́ ṣe ìpinnu kan tí kò rọrùn.
Ka ìwé yìí kó o lè túbọ̀ mọ bó o ṣe lè ṣohun tó máa múnú Jèhófà dùn nígbà tí kò bá sí òfin kan pàtó nínú Bíbélì nípa ohun tó o fẹ́ ṣe.
“Ṣé Ìgbà Tó O Bá Rí Òfin Bíbélì Lo Tó Lè Ṣe Ohun Tó Yẹ?” (Ilé Ìṣọ́, December 1, 2003)
-