-
Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tó Dára fún Ọkàn àti ÌleraJí!—2012 | January
-
-
“Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.”—ÒWE 14:30.
-
-
Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tó Dára fún Ọkàn àti ÌleraJí!—2012 | January
-
-
Nígbà tí ìwé kan tó ń jẹ́ Journal of the American College of Cardiology ń sọ̀rọ̀ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn èèyàn jẹ́jẹ́ àtàwọn tó sábà máa ń bínú, ó sọ pé: “Ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn tó bá ń bínú gan-an tí wọ́n sì jẹ́ òṣónú máa ń ní àrùn nínú iṣan tó máa ń gbé ẹ̀jẹ̀ wọnú ọkàn.” Ìwé náà tún wá sọ pé: ‘Béèyàn bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àrùn ọkàn yìí, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣíṣe eré ìmárale àti lílo oògùn nìkan, ó tún gba pé kí wọ́n ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣàkóso èrò inú wọn, kí wọ́n máa fiyè dénú, kí wọ́n má sì jẹ́ òṣónú.’ Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ gan-an ló ṣe rí. Bí èèyàn kì í bá bínú sódì, ó máa ń jẹ́ kí èèyàn ní ìlera tó dáa.
-