ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 4/8 ojú ìwé 24-26
  • Kí Ló Dé Tí N Kò Lè Ní Àwọn Ohun Tí Mo Ń Fẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Dé Tí N Kò Lè Ní Àwọn Ohun Tí Mo Ń Fẹ́?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Ohun Ìní
  • Nígbà Tí O Bá Nílò Ohun Kan Ní Gidi
  • Kọ́ Bí A Ṣe Ń Ní Ìtẹ́lọ́rùn
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lówó?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná?
    Jí!—2006
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Mọ Àwọn Òbí Mi?
    Jí!—2010
  • Kí Ni Kí N Ṣe Báwọn Òbí Mi Bá Ń Jà?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 4/8 ojú ìwé 24-26

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Dé Tí N Kò Lè Ní Àwọn Ohun Tí Mo Ń Fẹ́?

“Àwọn ohun kan wà tó dára gan-an, mo sì fẹ láti ní wọn; ṣùgbọ́n àwọn òbí mi kò lágbára àtirà wọ́n fún mi.”—Mike.

ǸJẸ́ àwọn ohun kan wà tí o ń fẹ́ ní ti gidi ṣùgbọ́n tí o kò lè ní? Bóyá o ti ní in lọ́kàn láti ní ẹ̀rọ amìjìnjìn tuntun yẹn, irú bàtà tí àwọn èwe mìíràn ń wọ̀, tàbí kí ó wulẹ̀ jẹ́ ṣòkòtò jeans tuntun tí ó ní àkọlé ẹni tó ṣeé lára. Àwọn ojúgbà rẹ kan ní irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀, wọ́n sì máa ń fi wọ́n yangàn. Nítorí náà, bí àwọn òbí rẹ bá sọ fún ọ pé àwọn kò lágbára àtirà wọ́n fún ọ, o lè nímọ̀lára ìjákulẹ̀.

Àmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ohun tó burú nínú fífẹ́ láti ní àwọn ohun kan, ìsúnniṣe tipátipá ló ń mú kí wọ́n fẹ́ láti ní wọn. Ó jọ pé púpọ̀ lára èyí jẹ́ ìyọrísí ohun tí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń gbé jáde. Àwọn ìpolówó ọjà tí a fi àrékérekè gbé kalẹ̀ nínú tẹlifíṣọ̀n, ìwé ìròyìn, àti rédíò ń gbé ìsọfúnni pé o kò já mọ́ nǹkan kan àyàfi bí o bá wọ irú àwọn aṣọ kan tàbí kí o lo àwọn ohun kan tí ó ní àkọlé ẹni tó ṣe wọ́n lára. Kódà, iye tí àwọn ọ̀dọ́ ń ná ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan lé ní ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù dọ́là lọ́dún!

Fífẹ́ láti ṣe ohun tí ojúgbà ẹni ń ṣe tún wà níbẹ̀. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Marketing Tools sọ pé: “Ní ọ̀nà ìgbésí ayé aláìmọ̀kan tí kò gba gbẹ̀rẹ́ tí àwọn ọ̀dọ́ ń gbé, jíjẹ́ ẹni tí àwùjọ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí o ń fẹ́ bá dọ́gba ń kà sí ẹni tí kò gbọ́ fáàrí kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn àìdójú ìlà ọ̀pá ìdíwọ̀n wọn, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ kọ̀ ọ́: ṣùgbọ́n ó jẹ́ àmì ìdánimọ̀ Ẹni Tí Kò Rọ́wọ́ Mú.” Kí ló wá ń pinnu jíjẹ́ ẹni tó “wà pa”? Nínú ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ, ohun tí ń pinnu rẹ̀ ni níní àwọn ohun tí ó dára jù lọ àti èyí tí ó dé kẹ́yìn. Bí o kò bá sì lè rà wọ́n ńkọ́? Èwe Kristẹni kan sọ pé: “Kò rọrùn rárá. Bí o bá wọ aṣọ tí kò ní àkọlé ẹni tó ṣe é lára lọ sí ilé ẹ̀kọ́, gbogbo ènìyàn yóò máa fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́.” Èwe mìíràn sọ pé, “Nígbà mìíràn, ó máa ń ṣe mí bíi pé n kò bẹ́gbẹ́ mu.”

Ìṣòro fífẹ́ láti bá ẹgbẹ́ dọ́gba yìí kan náà lè máa dààmú àwọn èwe tí ń gbé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, níbi tí àwọn èèyàn ti ń ṣe làálàá fún ọ̀pọ̀ wákàtí tí ó sì jẹ́ pé ekukáká ni wọ́n fi ń rí ìwọ̀nba àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé. Bí èyí bá ń ṣẹlẹ̀ sí ìdílé rẹ, lọ́nà tẹ̀dá, o lè máa yán hànhàn fún ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ dára. Nítorí pé o ti wo àwọn eré tí a kó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n, ìwọ pẹ̀lú lè ti bẹ̀rẹ̀ sí í yán hànhàn láti ní àwọn aṣọ, ibùgbé, àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ olówó ńlá tí a ń fi hàn nínú àwọn eré àti fíìmù wọ̀nyẹn. Nítorí pé àwọn ohun bẹ́ẹ̀ lè dà bí èyí tí o kò lè ní láé, inú rẹ lè bà jẹ́ tàbí kí o tilẹ̀ sorí kọ́.

Yálà orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀ tàbí èyí tí ó lọ́rọ̀ ni o ń gbé, bíbínú tàbí sísoríkọ́ nítorí pé o kò lè ní àwọn ohun kan wulẹ̀ lè pa ọ́ lára. Ó tún lè mú kí o máa ṣàkànrìn sí àwọn òbí rẹ léraléra. Ìbéèrè tó wá sọ́kàn ni pé, Báwo ni o ṣe lè kojú ipò náà?

Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Ohun Ìní

Lákọ̀ọ́kọ́, jẹ́ kí ó yé ọ pé kì í ṣe ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ wà ní ipò òṣì tàbí kí wọ́n máà ní àwọn ohun tí wọ́n nílò ní gidi. Ó ṣe tán, kì í ṣe orí àkìtàn ni Ọlọ́run fi Ádámù àti Éfà sí bí kò ṣe inú ọgbà ẹlẹ́wà kan tí ó kún fún igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò. (Jẹ́nẹ́sísì 2:9) Lẹ́yìn náà, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bí Ábúráhámù, Jóòbù, àti Sólómọ́nì ní ohun ìní púpọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 13:2; Jóòbù 1:3) Kódà, Sólómọ́nì ní wúrà tó pọ̀ gan-an débi pé fàdákà wá di ohun tí a kò kà sí “nǹkan kan rárá” nígbà ìṣàkóso rẹ̀!—1 Àwọn Ọba 10:21, 23.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lápapọ̀, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ènìyàn Ọlọ́run ló ní àwọn nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ jẹ́ aláìní; kò tilẹ̀ ní “ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Mátíù 8:20) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, o kò kà nípa Jésù rí pé ó ń ṣàròyé pé òun kò lágbára àtira àwọn ohun tí òun ń fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi kọ́ni pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ . . . Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:31-33.

Èyí kò túmọ̀ sí pé dandan-ǹ-dan ni Ọlọ́run yóò mú kí àwọn aṣọ tí ó ní àkọlé ẹni tó ṣe é lára tàbí àwọn ẹ̀rọ amìjìnjìn tí ẹnì kan ń yán hànhàn fún tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ọlọ́run ń pèsè àwọn ohun tí a nílò—kò fi dandan jẹ́ àwọn ohun tí a ń fẹ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rọ̀ wá láti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú kìkì “ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ.” (1 Tímótì 6:8) Ṣùgbọ́n ká sọ tòótọ́, kò rọrùn láti ní ìtẹ́lọ́rùn. Èwe kan tí ń jẹ́ Mike sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni wàá máa dààmú nípa èwo ló jẹ́ ohun tí o ń fẹ́ àti èyí tí o nílò.” Yàtọ̀ sí ìfẹ́-ọkàn onímọtara-ẹni-nìkan tiwa fúnra wa, a gbọ́dọ̀ gbéjà ko agbára Sátánì Èṣù, olórí elénìní Ọlọ́run. (1 Jòhánù 5:19) Ọ̀kan lára àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó ń lò ni láti mú kí àwọn ènìyàn máa lérò pé àwọn ń sọ àǹfààní kan nù. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ ríronú pé a ń fi nǹkan du òun—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń gbé inú párádísè pípé kan!—Jẹ́nẹ́sísì 3:2-6.

Báwo ni o ṣe lè yẹra fún kíkó sínú ọ̀fìn àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn? Ó lè dà bí ọ̀rọ̀ àsọtúnsọ látìgbàdégbà, àmọ́ ìdí púpọ̀ wà tí o fi ní láti ronú nípa àwọn ìbùkún tí o ti rí gbà. Má ṣe jẹ́ kí àwọn èrò òdì nípa ohun tí o kò ní fawọ́ aago rẹ sẹ́yìn. Máa ronú lọ́nà tó dára, kí o sì máa rán ara rẹ létí àwọn ohun tí o ní. (Fi wé Fílípì 4:8.) Mike sọ lọ́nà yìí pé: “Àwọn ohun tí mo ń fẹ́ gan-an kò kéré níye, àmọ́ n kì í jẹ́ kí wọ́n gbà mí lọ́kàn.”

Ó tún ń ṣàǹfààní láti fura sí àwọn ìpolówó ọjà tí ń lo àrékérekè láti ru ìmọ̀lára rẹ sókè.a (Òwe 14:15) Kí o tó kù gììrì dórí ìpinnu pé ó di dandan kí o ra bàtà tuntun yẹn tàbí ẹ̀rọ amìjìnjìn tí ike ìkósọfúnnisí ń kọrin nínú rẹ̀, gbìyànjú láti fara balẹ̀ ronú nípa rẹ̀ dáadáa. Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mo nílò ohun yìí ní gidi? Ǹjẹ́ ó wúlò fún ète pàtàkì kan? Àwọn ohun tí mo ti ní ha tó mi bí?’ Ní pàtàkì, ṣọ́ra fún àwọn ìpolówó ọjà tí ń gbé èrò níní nǹkan lárugẹ. Ohun tí ń múni ṣe wọ̀ọ̀ wà nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ nínú 1 Jòhánù 2:16 pé: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.”

Nígbà Tí O Bá Nílò Ohun Kan Ní Gidi

Ká ní o nílò ohun kan tí o lẹ́tọ̀ọ́ sí ní gidi ńkọ́? Rò ó wò dáadáa kí o tó bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Múra sílẹ̀ láti ṣàlàyé ìdí rẹ̀ gan-an tí o fi nílò ohun náà, bí o ṣe wéwèé láti lò ó, àti ìdí tí o fi lérò pé yóò wúlò fún ọ. Bóyá àwọn òbí rẹ yóò wá ọ̀nà láti fi í sínú ìwéwèé ìnáwó ìdílé yín. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá lágbára rẹ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ ńkọ́? O lè má lè ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀ ju pé kí o ní sùúrù. (Oníwàásù 7:8) “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ni a wà yìí, ọ̀pọ̀ òbí kò sì lágbára àtira gbogbo ohun tí àwọn ọmọ wọn lè béèrè fún. (2 Tímótì 3:1) Bí o kò bá fi bíbéèrè fún àwọn ohun tí kò ní láárí pá àwọn òbí rẹ lórí, o lè mú kí iṣẹ́ wọn tó ṣòro rọrùn díẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwọ alára ni yóò gbé ìgbésẹ̀ náà. Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ wọ́n máa ń fún ọ ní owó tí o lè mú ná? Nígbà náà, gbìyànjú láti kọ́ bí o ṣe máa fìṣọ́ra wéwèé owó rẹ kí o baà lè máa fi díẹ̀ nínú rẹ̀ pa mọ́ lóṣooṣù. Ó tilẹ̀ lè ṣeé ṣe kí o ṣí àkáǹtì ìfowópamọ́ sí báńkì kan nítòsí. (Fi wé Lúùkù 19:23.) Ohun tí ọmọdébìnrin kan tí ń jẹ́ Abigail ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo pín owó mi sí ọ̀nà méjì—apá kan ń lọ sínú àkáǹtì tí mo ní sí báńkì, èkejì ni mo sì máa ń ná.” Bí o bá ti dàgbà tó, o tilẹ̀ lè gbìyànjú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan tàbí iṣẹ́ àfipawọ́.b Bí ó ti wù kí ó rí, bí àwọn òbí rẹ bá rí i pé o fẹ́ ra ohun kan ní gidi àti pé o mú ọ̀rọ̀ fífi owó pa mọ́ lógìírí, ó lè sún wọn láti bá ọ san lára owó náà, bí ó bá ṣeé ṣe.

Ṣíṣe àwọn ìyípadà díẹ̀ nínú bí o ṣe máa ń rajà tún lè ṣàǹfààní fún ọ. Fún àpẹẹrẹ, bí ohun kan bá wọ́n jù, ó lè ṣeé ṣe láti lọ ná òmíràn tí kò wọ́n tó bẹ́ẹ̀. Bí ìyẹn kò bá ṣiṣẹ́, ní sùúrù, kí o sì wò ó bóyá ohun náà ṣì wà lórí àtẹ. Wo àwọn ilé ìtajà mìíràn láti rí i bóyá o lè rí ohun kan náà níye tí kò wọ́n jù. Kọ́ bí a ṣe ń yẹ ọjà wò dáadáa láti wò ó bóyá ojúlówó ni; nígbà mìíràn, àwọn ọjà tí kò ní àkọlé ẹni tó ṣe é lára máa ń dínwó gan-an.c

Kọ́ Bí A Ṣe Ń Ní Ìtẹ́lọ́rùn

Òwe 27:20 kìlọ̀ pé: “Ṣìọ́ọ̀lù àti ibi ìparun kì í ní ìtẹ́lọ́rùn; bẹ́ẹ̀ ni ojú ènìyàn kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.” Òtítọ́ ni, bí kò ti rọrùn láti tẹ́ ìyánhànhàn sàréè lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn sábà máa ń fẹ́ ohun púpọ̀ púpọ̀ sí i—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ní ohun tó pọ̀ tẹ́lẹ̀. Má ṣe ní irú èrò onímọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀. Ìjákulẹ̀ àti àìláyọ̀ ni ìwọra máa ń mú wá nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Èwe kan tí ń jẹ́ Jonathan sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ orí níní nǹkan ni o ń gbé ayọ̀ rẹ kà, o kò ní láyọ̀ láé. Kò sí ìgbà tí o kò ní fẹ́ láti ní ohun tuntun kan. O ní láti kọ́ bí o ṣe lè láyọ̀ pẹ̀lú ohun tí o ní.”

Bí o bá ní ìtẹ́lọ́rùn, o lè kápá ìsúnniṣe láti bá ẹgbẹ́ rẹ dọ́gba. Ọ̀dọ́mọdé Vincent sọ pé: “Kìkì nítorí pé mo rí ẹnì kan tí ó wọ bàtà tí ó ní àkọlé ẹni tó ṣe é lára kò túmọ̀ sí pé mo gbọ́dọ̀ ra irú rẹ̀.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, inú rẹ lè bàjẹ́ bí o kò bá lè ní ohun tí o ń fẹ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, má ṣe gbàgbé pé Jèhófà mọ àwọn ohun tí o nílò. (Mátíù 6:32) Àti pé láìpẹ́ láìjìnnà, òun yóò “tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—Sáàmù 145:16.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Ìpolówó Ọjà—Báwo Ló Ṣe Kàn Ọ́?,” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, August 22, 1998, Gẹ̀ẹ́sì.

b Wo àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Wá Owó?,” nínú ìtẹ̀jáde wa ti September 8, 1998.

c Fún àfikún ìsọfúnni tó wúlò, wo àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Àwọn Aṣọ Tí Mo Ní Sunwọ̀n Síi?,” nínú ìtẹ̀jáde wa ti January 22, 1995.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]

“Bí o bá wọ aṣọ tí kò ní àkọlé ẹni tó ṣe é lára lọ sí ilé ẹ̀kọ́, gbogbo ènìyàn yóò máa fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Bí o kò tilẹ̀ ní gbogbo ohun tí o ń fẹ́, o lè láyọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́