ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | August 1
    • Iwe Owe ni ninu ọpọlọpọ ẹsẹ ti o dá duro gedegbe gẹgẹ bi awọn gbolohun imọran alaifi bọpobọyọ, ṣugbọn Owe 27:23 jẹ apakan ninu awujọ awọn ẹsẹ: “Iwọ maa ṣaniyan lati mọ iwa agbo ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ. Nitori pe ọrọ̀ kii wà titilae: ade a ha sì maa wà dé irandiran? Koriko yọ, ati ọmunu koriko fi ara han, ati ewebẹ awọn oke kojọ pọ. Awọn ọdọ-agutan ni fun aṣọ rẹ, awọn obukọ si ni iye owo oko. Iwọ o si ni wara ewurẹ tó fun ounjẹ rẹ, fun ounjẹ awọn ara ile rẹ ati fun ounjẹ awọn iranṣẹbinrin rẹ.”—Owe 27:23-27.

  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | August 1
    • “Iṣura,” tabi ọrọ̀ ti a jere ninu idawọle okowo kiakia, pẹlu iyì (“ade”) ti o yọrisi le fi irọrun parẹ, gẹgẹ bi ọpọlọpọ ti le jẹrii sii. Ohun pupọ ni a le tipa bayii sọ ni itilẹhin fun igbesi-aye oniwọntunwọnsi, iru eyi ti awọn oluṣọ agutan igba atijọ ntẹle ni bibojuto agbo ẹran. Iru ọna igbesi-aye yẹn kii wulẹ ṣe oniwọntunwọnsi ni ero ti jijẹ alaibikita. Oluṣọ agutan kan nilati bojuto agbo ẹran rẹ̀ daradara, ni riri i daju pe awọn agutan naa ni a daabobo. (Saamu 23:4) Boya, ni fifun wọn ni afiyesi, oun ri agutan kan ti nṣaisan tabi ti o farapa, oun le da ororo atunilara le e lori. (Saamu 23:5; Esekiẹli 34:4; Sekaraya 11:16) Ninu awọn ọran ti o pọ julọ oluṣọ agutan alaapọn naa ti o nṣaniyan nipa agbo ẹran rẹ yoo ri pe awọn isapa oun mu eso jade—ibisi kẹrẹkẹrẹ ninu agbo ẹran rẹ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́