-
Ibeere Lati Ọwọ Awọn OnkaweIlé-Ìṣọ́nà—1991 | August 1
-
-
Iwe Owe ni ninu ọpọlọpọ ẹsẹ ti o dá duro gedegbe gẹgẹ bi awọn gbolohun imọran alaifi bọpobọyọ, ṣugbọn Owe 27:23 jẹ apakan ninu awujọ awọn ẹsẹ: “Iwọ maa ṣaniyan lati mọ iwa agbo ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ. Nitori pe ọrọ̀ kii wà titilae: ade a ha sì maa wà dé irandiran? Koriko yọ, ati ọmunu koriko fi ara han, ati ewebẹ awọn oke kojọ pọ. Awọn ọdọ-agutan ni fun aṣọ rẹ, awọn obukọ si ni iye owo oko. Iwọ o si ni wara ewurẹ tó fun ounjẹ rẹ, fun ounjẹ awọn ara ile rẹ ati fun ounjẹ awọn iranṣẹbinrin rẹ.”—Owe 27:23-27.
-
-
Ibeere Lati Ọwọ Awọn OnkaweIlé-Ìṣọ́nà—1991 | August 1
-
-
Oluṣọ agutan oṣiṣẹ kára ti o si jẹ oluṣọra ni orisun iranwọ ti o ṣee gbarale—Jehofa. Bawo ni o ṣe jẹ bẹẹ? O dara, Ọlọrun npese awọn asiko ati iyipo ti o saba maa nyọri si koriko ti o to lati bọ́ agbo ẹran naa. (Saamu 145:16) Nigba ti awọn akoko ba yipada, ti papa tutu ko sì sí mọ ni pẹtẹlẹ, o le wà lọpọ yanturu ni awọn oke, nibiti oluṣọ agutan alafiyesi daradara kan le kó awọn ẹran rẹ lọ.
-