ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ni Àwọn Ohun Alààyè Kọ́ Wa?
    Jí!—2006 | September
    • Wọ́n Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àtẹ́lẹsẹ̀ Ọmọńlé

      A tún lè kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lára àwọn ẹranko. Bí àpẹẹrẹ, ọmọńlé lè pọ́n ògiri, ó sì lè lẹ̀ mọ́ àjà típẹ́típẹ́ láì jábọ́. Kódà lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n mọ̀ pé ọmọńlé ní ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (Òwe 30:28) Ọgbọ́n wo ni ọmọńlé ń dá tí kì í fi í já bọ́?

      Àwọn nǹkan tíntìntín tó dà bí irun ní àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọńlé ló máa ń jẹ́ kó lè lẹ̀ mọ́ nǹkan, kódà bí ohun náà tiẹ̀ ń dán bíi gíláàsì. Kì í ṣe pé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ ní gọ́ọ̀mù tó fi ń lẹ̀ mọ́ nǹkan, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń lo ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pè ní agbára òòlẹ̀. Agbára òòlẹ̀ yìí ló máa ń jẹ́ kí ohun méjì lẹ̀ pa pọ̀ láì tú ká. Àwa èèyàn ò lè lẹ àtẹ́lẹwọ́ wa mọ́ ògiri ká sì máa pọ́n ọn bíi ti ọmọńlé, torí pé agbára òòfà kò ní jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ti ọmọńlé yàtọ̀, àwọn nǹkan tíntìntín tó dà bí irun ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ ló máa ń jẹ́ kí agbára òòlẹ̀ pọ̀ sí i táá sì mú kó borí agbára òòfà. Tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún nǹkan tíntìntín tó dà bí irun yìí bá lẹ̀ mọ́ ibì kan, ó máa ń jẹ́ kí agbára tí ọmọńlé ní láti lẹ̀ mọ́ nǹkan pọ̀ sí i, ìyẹn ni kì í sì í jẹ́ kó já bọ́.

      Kí la lè fi ohun tí wọ́n ṣàwárí lára ọmọńlé ṣe? Tí wọ́n bá wo àwọn nǹkan tíntìntín tó dà bí irun ní àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọńlé láti ṣe òòlẹ̀ onírun, ó máa dáa ju èyí tó wà báyìí tí wọ́n ń pè níVelcroa lọ. Ìwé ìròyìn The Economist sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó ń ṣèwádìí tó sọ pé tí wọ́n bá lè ṣe “òòlẹ̀ tó dà bí àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọńlé,” ó máa wúlò gan-an nínú “ìṣègùn nígbà tí kẹ́míkà tí wọ́n fi ń lẹ nǹkan pọ̀ kò bá ṣeé lò.”

  • Kí Ni Àwọn Ohun Alààyè Kọ́ Wa?
    Jí!—2006 | September
    • Àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọńlé kì í dọ̀tí, èèyàn ò lè rí ipa ẹsẹ̀ rẹ̀, kò síbi tí kò lè lẹ̀ mọ́, àfi ara ohun kan tí wọ́n ń pè ní Teflon, wẹ́rẹ́ ni ọmọńlé máa ń lẹ̀ mọ́ ara nǹkan, wẹ́rẹ́ báyìí náà ló sì máa ń ṣí kúrò lára ohun tó bá lẹ̀ mọ́. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó jọ èyí

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́