ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìwé Kan Tí Ó Wúlò Fún Ìgbésí Ayé Òde Òní
    Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
    • Ìlera ti ara ìyára ẹnì kan ni ipò tí ìlera ọpọlọ rẹ̀ àti ti èrò ìmọ̀lára rẹ̀ wà sábà máa ń nípa lé lórí. Fún àpẹẹrẹ, ìwádìí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu f ìdí ipa aṣèpalára tí ìbínú máa ń ní múlẹ̀. Nínú ìwé wọn, Anger Kills, Dókítà Redford Williams, Alábòójútó Ìwádìí Nípa Ìhùwàsí ní Duke University Medical Center, àti aya rẹ̀, Virginia Williams, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹ̀rí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fi hàn pé àwọn ènìyàn aláìníwàbí-ọ̀rẹ́ ni wọ́n wà nínú ewu níní àrùn ọkàn (àti àwọn àìsàn míràn) jù nítorí àwọn ìdí púpọ̀, títí kan níní ìwọ̀nba ọ̀rẹ́, àlékún ìrusókè nínú ìṣiṣẹ́ ara nígbà tí a bá mú un bínú àti àlékún nínú sísọ àwọn ìwà tí ó léwu fún ìlera di bárakú.”13

      Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí irú ìwádìí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu bẹ́ẹ̀ tó wáyé, Bíbélì ti fi àwọn èdè ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn tí ó sì yéni sọ ìsopọ̀ láàárín ipò èrò ìmọ̀lára àti ti ìlera ara ìyára wa pé: “Ọkàn àyà pípa rọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara, ṣùgbọ́n owú jẹ́ ìjẹrà fún àwọn egungun.” (Òwe 14:30; 17:22) Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, Bíbélì fúnni nímọ̀ràn pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀,” àti “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya [tàbí “bínú,” King James Version].”—Sáàmù 37:8; Oníwàásù 7:9.

  • Ìwé Kan Tí Ó Wúlò Fún Ìgbésí Ayé Òde Òní
    Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
    • “Má ṣe kánjú láti f ìbínú hàn; nítorí àwọn òmùgọ̀ ní ń gbin ìbínú sọ́kàn.” (Oníwàásù 7:9, The New English Bible) Ìmọ̀lára ni ó sábà máa ń ṣáájú àwọn ìgbégbèésẹ̀. Ẹni tí ó bá ń yára bínú jẹ́ òmùgọ̀, nítorí ipa ọ̀nà rẹ̀ lè ṣamọ̀nà sí àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe oníwàǹwára.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́