ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ǹjẹ́ Ò Ń ṣe Gbogbo Ojúṣe Rẹ Níwájú Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́—1999 | November 15
    • 12. Lọ́rọ̀ ara rẹ, báwo ni wàá ṣe sọ ohun tí Sólómọ́nì wí, gẹ́gẹ́ báa ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Oníwàásù 12:11, 12?

      12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ́n ìtẹ̀wé ti òde òní kò tíì sí nígbà ayé Sólómọ́nì, ìwé pọ̀ rẹpẹtẹ nígbà yẹn. Ojú wo ló yẹ kó fi wo irú ìwé bẹ́ẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún? Ó wí pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣó tí a gbá wọlé ni àwọn tí ó jọ̀wọ́ ara wọn fún àkójọ àwọn gbólóhùn; láti ọ̀dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan ni a ti fi wọ́n fúnni. Ní ti ohunkóhun yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí, ọmọ mi, gba ìkìlọ̀: Nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, òpin kò sí, fífi ara ẹni fún wọn lápọ̀jù sì ń mú ẹran ara ṣàárẹ̀.”—Oníwàásù 12:11, 12.

  • Ǹjẹ́ Ò Ń ṣe Gbogbo Ojúṣe Rẹ Níwájú Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́—1999 | November 15
    • 14. (a) Irú àwọn ìwé wo ni kò ní dáa kí èèyàn fi ‘ara rẹ̀ fún lápọ̀jù’? (b) Àwọn ìwé wo ló yẹ ká máa kà jù lọ, èé sì ti ṣe?

      14 Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí Sólómọ́nì fi sọ ohun tó sọ nípa ìwé? Tóò, táa bá fi ìwé ayé yìí wé Ọ̀rọ̀ Jèhófà, lóòótọ́ ni ìwé ayé pọ̀ rẹpẹtẹ, àmọ́, èrò ènìyàn lásán ló kúnnú ẹ̀. Èyí tó sì pọ̀ jù lọ nínú ìrònú yìí ló jẹ́ ti Sátánì Èṣù. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Nítorí náà, “fífi ara ẹni fún” irú àwọn ìwé ayé bẹ́ẹ̀ “lápọ̀jù” kò lè mú àǹfààní pípẹ́ títí wá. Ká sòótọ́, tíwèé ayé bá ti lọ pọ̀ jù, ó lè ba ipò tẹ̀mí èèyàn jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì, ẹ jẹ́ ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ìgbésí ayé. Èyí ni yóò fún ìgbàgbọ́ wa lókun, tí yóò sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Kíka àwọn ìwé mìíràn tàbí àwọn orísun ẹ̀kọ́ mìíràn lákàjù lè mú kí àárẹ̀ mú wa. Pàápàá jù lọ bírú ìwé bẹ́ẹ̀ bá lọ jẹ́ èyí tó kún fún ìrònú ayé tó ta ko ọgbọ́n Ọlọ́run, wọn ò dáa rárá, wọ́n sì lè pa ìgbàgbọ́ téèyàn ní nínú Ọlọ́run àti ète rẹ̀ kú pátápátá. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rántí pé ìwé tó ṣàǹfààní jù lọ nígbà ayé Sólómọ́nì àti lóde ìwòyí ni ìwé tó fi ọgbọ́n “olùṣọ́ àgùntàn kan” hàn, ìyẹn ni Jèhófà Ọlọ́run. Ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin ló pèsè sínú Ìwé Mímọ́, ìwọ̀nyí ló sì yẹ ká máa kà jù lọ. Bíbélì àti àwọn ìwé tó lè ranni lọ́wọ́ tí ‘ẹrú olóòótọ́’ náà ń tẹ̀ jáde ń jẹ́ ká ní “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”—Òwe 2:1-6.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́