-
Wòlíì Ayé Àtijọ́ Tó Jíṣẹ́ Tó Bóde Òní MuÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
Olódodo Lákòókò Rúkèrúdò
4. Ta ni Aísáyà, ìgbà wo ló sì jẹ́ wòlíì Jèhófà?
4 Aísáyà sọ nínú ẹsẹ àkọ́kọ́ ìwé rẹ̀ pé òun jẹ́ “ọmọkùnrin Émọ́sì,”a ó sì sọ fún wa pé òun ṣe iṣẹ́ wòlíì Ọlọ́run “ní àwọn ọjọ́ Ùsáyà, Jótámù, Áhásì àti Hesekáyà, àwọn ọba Júdà.” (Aísáyà 1:1) Èyí túmọ̀ sí pé, ó kéré tán, ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta ni Aísáyà fi ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì tí ń jíṣẹ́ Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Júdà, bóyá ó bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìparí ìjọba Ùsáyà—ní nǹkan bí ọdún 778 ṣááju Sànmánì Tiwa.
-
-
Wòlíì Ayé Àtijọ́ Tó Jíṣẹ́ Tó Bóde Òní MuÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
a Ká má ṣi Émọ́sì baba Aísáyà gbé fún Ámósì tó sàsọtẹ́lẹ̀ nígbà ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Ùsáyà, tó sì tún jẹ́ pé òun náà ló kọ ìwé Bíbélì tí ń jórúkọ rẹ̀.
-