-
Ta Ló Ṣe Àwọn Òfin Tó Ń Darí Àwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run?Ilé Ìṣọ́—2011 | July 1
-
-
1. Ṣé Àwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run Kò Lè Tóbi Ju Bí Wọ́n Ṣe Wà Lọ?
Ọ̀gbẹ́ni Aristotle sọ pé àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run kò lè tóbi ju bí wọ́n ṣe wà lọ. Àgbá tí ìràwọ̀ rọ̀ mọ́ kò lè sún kì tàbí kí ó tóbi ju bí ó ṣe wà lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àgbá yòókù.
Ǹjẹ́ ohun tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni Bíbélì sọ bíi ti Aristotle? Rárá o, Bíbélì kò ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí ní tààràtà. Àmọ́ wo ọ̀rọ̀ alárinrin tó fi ṣàpèjúwe kókó náà, ó ní: “Ẹnì kan wà tí ń gbé orí òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ dà bí tata, Ẹni tí ó na ọ̀run gẹ́gẹ́ bí aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oníhò wínníwínní, tí ó tẹ́ ẹ bí àgọ́ láti máa gbé inú rẹ̀.”—Aísáyà 40:22.a
Èwo ló tọ̀nà nínú méjèèjì lónìí, ṣé àwọn àgbá tí Aristotle ṣe ni àbí àpèjúwe tí Bíbélì ṣe nípa bí ayé ṣe rí? Lóde òní, kí ni ìwádìí nípa àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run sọ nípa ọ̀ràn yìí? Ó jọ àwọn onímọ̀ nípa sánmà lójú gan-an ní ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún láti mọ̀ pé àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run lè tóbi sí i. Kódà, ó jọ pé àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ máa ń já sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ṣàṣà àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, bí wọ́n bá tiẹ̀ wà, ló rò ó tẹ́lẹ̀ rí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀. Lónìí, àwọn onímọ̀ nípa àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run gbà gbọ́ pé, ṣe ni ọ̀run bẹ̀rẹ̀ láti ibi kékeré, tó sì ń fẹ̀ síwájú sí i láti ìgbà yẹn wá. Ní kúkúrú, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti sọ àwọn àgbá tí Aristotle ṣe yẹn di ohun tí kò wúlò mọ́.
Ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ ńkọ́? Kò ṣòro láti fojú inú wo wòlíì Aísáyà bó ṣe ń wo ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀, tó sì rí i pé ojú ọ̀run tẹ́ rẹrẹ bí àgọ́ tí wọ́n nà jáde.b Ó tiẹ̀ ti lè ṣàkíyèsí bí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà ṣe jọ “aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oníhò wínníwínní.”
Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ Aísáyà mú ká fojú inú yàwòrán ohun tó sọ. Tá a bá fojú inú wo àgọ́ tí wọ́n ń lò ní àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì, ó ṣeé ṣe ká rí ìdì aṣọ kékeré tí wọ́n nà jáde, kí wọ́n tó fi bo orí àwọn òpó, tí wọ́n fi ṣe àgọ́ téèyàn lè gbé inú rẹ̀. Bákan náà, a lè fojú inú wo oníṣòwò kan tó gbé ìdì aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oníhò wínníwínní, tó nà án sílẹ̀ kí oníbàárà rẹ̀ lè yẹ̀ ẹ́ wò. Nínú ọ̀ràn méjèèjì yìí, ìdì kékeré kan ni wọ́n nà jáde àmọ́ ó fẹ̀ sí i nígbà tí wọ́n nà án.
Àmọ́ ṣá o, a kò sọ pé àkàwé tí Bíbélì fi àgọ́ àti aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oníhò wínníwínní ṣe wá túmọ̀ sí pé àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run máa ń tóbi sí i. Ṣùgbọ́n, ṣé kò jọni lójú pé àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa ojú ọ̀run bá èyí tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ṣe mú gan-an? Aísáyà gbé láyé ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta ṣáájú ìgbà ayé Aristotle, ìyẹn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan ṣáájú kí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó fúnni ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípa ọ̀ràn yìí. Síbẹ̀, kò sídìí fún ṣíṣe àtúnṣe sí ohun tí wòlíì Hébérù onírẹ̀lẹ̀ yẹn ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀, àmọ́ wọ́n ṣàtúnṣe sí èrò Aristotle nípa àgbá tó hùmọ̀.
-
-
Ta Ló Ṣe Àwọn Òfin Tó Ń Darí Àwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run?Ilé Ìṣọ́—2011 | July 1
-
-
a Ó jọni lójú gan-an pé Bíbélì pe ayé ní òbìrìkìtì tàbí àgbá, ìyẹn ọ̀nà míì tí wọ́n lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà sí. Ọ̀gbẹ́ni Aristotle àti àwọn ará Gíríìsì ayé ìgbàanì tiẹ̀ dábàá pé ayé rí roboto, síbẹ̀, wọ́n ṣì ń jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn náà.
-