ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Wò ó! Ìránṣẹ́ Tí Jèhófà Tẹ́wọ́ Gbà
    Ilé Ìṣọ́—2009 | January 15
    • 4 Nígbà tí Jésù ṣì wà lọ́mọ ọwọ́, ẹ̀mí mímọ́ mú kí ọkùnrin olódodo kan tó ń jẹ́ Síméónì kéde pé “ọmọ kékeré náà Jésù” yóò di “ìmọ́lẹ̀ fún mímú ìbòjú kúrò lójú àwọn orílẹ̀-èdè,” gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 42:6 àti 49:6 ṣe fi hàn. (Lúùkù 2:25-32) Bákan náà, ìwọ̀sí tí wọ́n fi lọ Jésù lóru ọjọ́ tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ wà lára ohun tí Aísáyà 50:6-9 ti sọ tẹ́lẹ̀. (Mát. 26:67; Lúùkù 22:63) Lẹ́yìn àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pétérù fi hàn kedere pé Jésù ni “Ìránṣẹ́” Jèhófà yẹn. (Aísá. 52:13; 53:11; ka Ìṣe 3:13, 26.) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà yìí?

  • Wò ó! Ìránṣẹ́ Tí Jèhófà Tẹ́wọ́ Gbà
    Ilé Ìṣọ́—2009 | January 15
    • Ó Jẹ́ “Ìmọ́lẹ̀” àti “Májẹ̀mú”

      11. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀nà wo ló sì gbà jẹ́ bẹ́ẹ̀ títí dòní?

      11 Àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 42:6 ṣẹ sí Jésù lára ní ti pé ó jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” lóòótọ́. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ọ̀dọ̀ àwọn Júù ló mú ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere wá ní pàtàkì. (Mát. 15:24; Ìṣe 3:26) Ṣùgbọ́n Jésù tún sọ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Jòh. 8:12) Yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fáwọn Júù àtàwọn orílẹ̀-èdè ní ti pé ó là wọ́n lóye nípa tẹ̀mí, ó tún jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún wọn ní ti pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé rúbọ kó lè ra gbogbo aráyé pátá pa dà. (Mát. 20:28) Lẹ́yìn tó jíǹde, ó ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣe ẹlẹ́rìí òun “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń wàásù, wọ́n ṣàyọlò ọ̀rọ̀ náà, “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” látinú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, wọ́n ní àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ló ń ní ìmúṣẹ báwọn ṣe ń wàásù fáwọn tí kì í ṣe Júù. (Ìṣe 13:46-48; fi wé Aísáyà 49:6.) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ṣì ń bá a lọ títí dòní, bí àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin Jésù lórí ilẹ̀ ayé àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ṣe ń tan ìhìn rere káàkiri, tí wọ́n sì ń mú káwọn èèyàn nígbàgbọ́ nínú Jésù, tó jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.”

      12. Báwo ni Jèhófà ṣe fi Ìránṣẹ́ rẹ̀ fúnni “gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú àwọn ènìyàn”?

      12 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, Jèhófà sọ fún Ìránṣẹ́ rẹ̀ tó yàn pé: “Èmi yóò sì máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, èmi yóò sì fi ọ́ fúnni gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú àwọn ènìyàn.” (Aísá. 42:6) Sátánì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣekú pa Jésù, kí Jésù má bàa lè parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wá ṣe láyé, àmọ́ Jèhófà dáàbò bò ó títí di ìgbà tó yẹ kó kú. (Mát. 2:13; Jòh. 7:30) Lẹ́yìn náà, Jèhófà jí Jésù dìde, ó sì fi í fún àwa ọmọ aráyé gẹ́gẹ́ bí “májẹ̀mú” tàbí ẹ̀jẹ́. Ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ yìí mú kó dájú pé Ìránṣẹ́ Ọlọ́run olóòótọ́ yìí yóò jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” yóò sì máa mú àwọn èèyàn kúrò nínú òkùnkùn tẹ̀mí.—Ka Aísáyà 49:8, 9.b

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́