ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Rí Ìtumọ̀ Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Kan
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 2. (a) Orúkọ oyè wo ni Jésù pe ara rẹ̀? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ, pé “Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ èmi sì ni ẹni ìkẹyìn” túmọ̀ sí? (d) Kí ni orúkọ oyè Jésù náà “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn” pe àfiyèsí sí?

      2 Àmọ́ ṣá o, kò yẹ kí ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tá a ní fa ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì fún wa. Jésù fi àpọ́sítélì Jòhánù lọ́kàn balẹ̀, ìyẹn sì lohun tí Jòhánù sọ tẹ̀ lé e. Ó ní: “Ó sì gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó sì wí pé: ‘Má bẹ̀rù. Èmi ni Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn, àti alààyè.’” (Ìṣípayá 1:17b, 18a) Nínú Aísáyà 44:6, Jèhófà fi ẹ̀tọ́ sọ ipò tóun wà, ó ní òun nìkan ni Ọlọ́run Olódùmarè. Bó ṣe sọ ọ́ rèé: “Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, yàtọ̀ sí mi, kò sí Ọlọ́run kankan.”a Nígbà tí Jésù lo orúkọ oyè náà “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn” fún ara rẹ̀, kò sọ pé òun bá Jèhófà tó jẹ́ Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá dọ́gba. Ọlọ́run ló fi orúkọ oyè tó lò yìí jíǹkí rẹ̀ lọ́nà ẹ̀tọ́. Nínú ìwé Aísáyà yẹn, Jèhófà sọ pé ipò Òun ò lẹ́gbẹ́, pé Òun ni Ọlọ́run tòótọ́ náà. Òun ni Ọlọ́run ayérayé, àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí òun. (1 Tímótì 1:17) Nínú ìwé Ìṣípayá, nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa orúkọ oyè tí Ọlọ́run fi jíǹkí rẹ̀, àjíǹde rẹ̀ tó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ló ń pe àfiyèsí sí.

  • A Rí Ìtumọ̀ Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Kan
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • a Nínú èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ Bíbélì, Aísáyà 44:6 kò lo ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń tọ́ka nǹkan pàtó mọ́ ọ̀rọ̀ náà, “àkọ́kọ́” àti “ìkẹyìn.” Àmọ́ Jésù lo ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń tọ́ka nǹkan pàtó nínú èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì nígbà tó sọ ohun tó wà ní Ìṣípayá 1:17. Nítorí náà, tá a bá fi ìlànà gírámà wò ó, orúkọ oyè ni Ìṣípayá 1:17 fi hàn, nígbà tó jẹ́ pé Aísáyà 44:6 ṣàpèjúwe jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́