ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ẹ Jẹ́ Kí A Mú Àwọn Ọ̀ràn Tọ́”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • 1, 2. Ta ni Jèhófà fi àwọn ọba àtàwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù àti Júdà wé, èé sì ti ṣe tí èyí fi tọ́?

      ÀWỌN olùgbé Jerúsálẹ́mù lè fẹ́ máa dá ara wọn láre lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìbáwí kíkankíkan tó wà nínú Aísáyà 1:1-9. Ó dájú pé wọ́n á fẹ́ máa fi gbogbo ẹbọ tí wọ́n ń rú sí Jèhófà yangàn. Àmọ́, ẹsẹ kẹwàá sí ìkẹẹ̀ẹ́dógún sọ èsì tí Jèhófà fi bẹnu àtẹ́ lu irú ìwà bẹ́ẹ̀. Ó lọ báyìí pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin apàṣẹwàá Sódómù. Ẹ fi etí sí òfin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn Gòmórà.”—Aísáyà 1:10.

      2 Kì í ṣe tìtorí ìṣekúṣe nìkan ni wọ́n fi pa Sódómù àti Gòmórà run, oríkunkun àti ìgbéraga pẹ̀lú ohun tó fà á. (Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21; 19:4, 5, 23-25; Ìsíkíẹ́lì 16:49, 50) Ó ní láti jẹ́ pé ńṣe làyà àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Aísáyà kó sókè bí wọ́n ṣe gbọ́ tó ń fi wọ́n wé àwọn ènìyàn ìlú ègún wọ̀nyẹn.a Ṣùgbọ́n Jèhófà mọ irú ẹni tí àwọn èèyàn rẹ̀ yà, Aísáyà ò sì ní bomi la ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run láti lè “rìn wọ́n ní etí.”—2 Tímótì 4:3.

  • “Ẹ Jẹ́ Kí A Mú Àwọn Ọ̀ràn Tọ́”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • a Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù àtijọ́ ṣe wí, ṣe ni Mánásè Ọba burúkú ní kí wọ́n pa Aísáyà, pé kí wọ́n fi ayùn rẹ́ ẹ sí méjì. (Fi wé Hébérù 11:37.) Ìwé ìtàn kan sọ pé, kí wọ́n bàa lè rí ìdájọ́ ikú yẹn dá fún Aísáyà, ẹ̀sùn tí wòlíì èké kan fi kàn án ni pé: “Ó pe Jerúsálẹ́mù ní Sódómù, ó sì sọ pé àwọn ọmọ aládé Júdà àti Jerúsálẹ́mù jẹ́ ará Gòmórà.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́