-
Ìsìn Èké—Ìran Fi Hàn Pé Yóò Lọ LáúÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
19 Àmọ́ Jèhófà wá fi í ṣẹlẹ́yà pé: “Àárẹ̀ ti mú ọ pẹ̀lú ògìdìgbó àwọn tí ń gbà ọ́ nímọ̀ràn. Kí wọ́n dìde dúró, nísinsìnyí, kí wọ́n sì gbà ọ́ là, àwọn tí ń jọ́sìn ọ̀run, àwọn tí ń wo ìràwọ̀, àwọn tí ń fúnni ní ìmọ̀ nígbà òṣùpá tuntun nípa àwọn ohun tí yóò dé bá ọ.” (Aísáyà 47:13)e Ìjákulẹ̀ yóò bá Bábílónì bí àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ yóò ṣe kùnà pátápátá. Òótọ́ ni pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ìrírí lẹ́nu ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sánmà ni àwọn awòràwọ̀ Bábílónì yóò ti ní, tí wọ́n sì ń lò. Ṣùgbọ́n bí àwọn awòràwọ̀ rẹ̀ yóò ṣe kùnà pátápátá lálẹ́ ọjọ́ tí yóò ṣubú ni yóò táṣìírí iṣẹ́ wíwò pé asán ni.—Dáníẹ́lì 5:7, 8.
-
-
Ìsìn Èké—Ìran Fi Hàn Pé Yóò Lọ LáúÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
e Ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “àwọn tí ń jọ́sìn ọ̀run” ni àwọn kan túmọ̀ sí “àwọn tó pín ọ̀run sí onírúurú ọ̀nà.” Àṣà pípín ọ̀run sí onírúurú ẹ̀ka láti fi wòràwọ̀ ni èyí ń sọ o.
-