ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jèhófà Gbé Mèsáyà Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Ga
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • ‘Ó Jẹ́ Kí A Ṣẹ́ Òun Níṣẹ̀ẹ́’

      25. Báwo la ṣe mọ̀ pé ńṣe ni Mèsáyà yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti jìyà àti láti kú?

      25 Ǹjẹ́ Mèsáyà fẹ́ láti jìyà kí ó sì kú? Aísáyà sọ pé: “A ni ín lára dé góńgó, ó sì jẹ́ kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́; síbẹ̀síbẹ̀, kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀. A ń mú un bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn fún ìfikúpa; àti bí abo àgùntàn tí ó yadi níwájú àwọn olùrẹ́run rẹ̀, òun kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀ pẹ̀lú.” (Aísáyà 53:7) Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ká ní pé ó fẹ́ ni, ì bá ti pe “àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá” lọ pé kí wọ́n wá gba òun sílẹ̀. Àmọ́ ó sọ pé: “Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí?” (Mátíù 26:53, 54) Dípò èyí, “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run” yìí kò janpata rárá ni. (Jòhánù 1:29) Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà fẹ̀sùn èké kan Jésù níwájú Pílátù, Jésù “kò dáhùn.” (Mátíù 27:11-14) Kò fẹ́ sọ ohunkóhun tó lè ṣèdíwọ́ fún ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fi òun ṣe. Jésù ṣe tán láti kú gẹ́gẹ́ bí Ọ̀dọ́ Àgùntàn táa fi rúbọ, nítorí ó mọ̀ dájúdájú pé ikú òun yóò ra àwọn onígbọràn nínú ọmọ aráyé padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, àìsàn, àti ikú.

  • Jèhófà Gbé Mèsáyà Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Ga
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 206]

      “Kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀”

      [Credit Line]

      Ara àwòrán inú “Ecce Homo” látọwọ́ Antonio Ciseri

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́