-
Ìsìn Tòótọ́ Gbilẹ̀ Kárí AyéÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
13. Lóde òní, àwọn wo ni àwọn “ọmọkùnrin” àti “ọmọbìnrin,” àwọn wo sì ni “ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè”?
13 Àpèjúwe tí Aísáyà 60:4-9 ṣe nípa bí ìsìn mímọ́ ṣe gbilẹ̀ kárí ayé láti ìgbà tí “obìnrin” Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí tan ìmọ́lẹ̀ láàárín òkùnkùn ayé yìí mà kúkú ṣe kedere o! Àwọn “ọmọkùnrin” àti “ọmọbìnrin” Síónì ti ọ̀run, tó di Kristẹni ẹni àmì òróró ni wọ́n kọ́kọ́ dé. Lọ́dún 1931, àwọn wọ̀nyí kéde fáyé gbọ́ pé àwọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, àwọsánmà àwọn ọlọ́kàn tútù, “àní ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” àti “ọlà òkun,” sáré wá dára pọ̀ mọ́ àwọn àṣẹ́kù lára àwọn arákùnrin Kristi.b Lóde òní, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí, tí wọ́n wá láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti láti onírúurú ẹ̀ka ìgbésí ayé ló ń dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run láti yin Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, àti láti gbé orúkọ rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí orúkọ tó tóbi lọ́lá jù lọ láyé àti lọ́run.
-
-
Ìsìn Tòótọ́ Gbilẹ̀ Kárí AyéÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
b Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni onítara tó ń ṣe déédéé, tí wọ́n ń retí láti wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé ti ń dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run ṣáájú ọdún 1930, ọdún 1930 síwájú ló hàn gbangba pé iye wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i.
-