ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Òdodo Rú Jáde ní Síónì
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • 16. Àwọn wo ló ń ran àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò yìí, iṣẹ́ wo ni wọ́n sì ń ṣe?

      16 Iṣẹ́ bàǹtàbanta lèyí jẹ́. Báwo ni àwọn kéréje tó ṣẹ́ kù nínú Ísírẹ́lì Ọlọ́run yìí yóò ṣe lè ṣe iṣẹ́ ńlá yìí láṣeparí? Jèhófà mí sí Aísáyà pé kí ó kéde pé: “Àwọn àjèjì yóò sì dúró ní ti tòótọ́, wọn yóò sì máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn agbo ẹran yín, àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè sì ni yóò jẹ́ àgbẹ̀ yín àti olùrẹ́wọ́ àjàrà yín.” (Aísáyà 61:5) Àwọn àjèjì àti àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè wọ̀nyí ṣàpẹẹrẹ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù.a (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:11, 16) Wọn kò gba ẹ̀mí mímọ́ lọ́nà ti pé kí wọ́n lọ gba ogún ní ọ̀run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń retí láti gba ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 21:3, 4) Síbẹ̀, wọ́n fẹ́ràn Jèhófà, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, iṣẹ́ àgbẹ̀, àti olùrẹ́wọ́ àjàrà. Iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kọ́ niṣẹ́ wọ̀nyẹn rárá. Àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyí ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn, wọ́n ń ṣètọ́jú àwọn èèyàn, wọ́n sì ń kórè wọn wọlé lábẹ́ àbójútó àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì Ọlọ́run.—Lúùkù 10:2; Ìṣe 20:28; 1 Pétérù 5:2; Ìṣípayá 14:15, 16.

  • Òdodo Rú Jáde ní Síónì
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • a Ó ṣeé ṣe kí Aísáyà 61:5 ṣẹ láyé àtijọ́, nítorí àwọn tí kì í ṣe Júù àbínibí bá àwọn Júù àbínibí padà wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ṣèrànwọ́ láti mú ilẹ̀ náà padà bọ̀ sípò. (Ẹ́sírà 2:43-58) Àmọ́, ó jọ pé kìkì àwọn Ísírẹ́lì Ọlọ́run ni ẹsẹ kẹfà síwájú kàn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́