-
Òdodo Rú Jáde ní SíónìÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
17. (a) Kí ni a óò máa pe àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run? (b) Ẹbọ kan ṣoṣo wo ni a nílò fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀?
17 Ísírẹ́lì Ọlọ́run wá ńkọ́ o? Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ fún wọn pé: “Ní ti ẹ̀yin, àlùfáà Jèhófà ni a óò máa pè yín; òjíṣẹ́ Ọlọ́run wa ni a ó sọ pé ẹ̀yin jẹ́. Ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ni ẹ ó jẹ, inú ògo wọn sì ni ẹ ó ti máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó kún fún ayọ̀ nípa ara yín.” (Aísáyà 61:6) Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, Jèhófà gbé ẹgbẹ́ àlùfáà ti àwọn ọmọ Léfì kalẹ̀ pé kí wọ́n máa bá àwọn àlùfáà fúnra wọn àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ wọn rúbọ. Àmọ́, lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa, Jèhófà ṣíwọ́ lílo ẹgbẹ́ àlùfáà ti àwọn ọmọ Léfì, ó sì fi ìṣètò tó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́lẹ̀. Ó tẹ́wọ́ gba ìwàláàyè pípé ti Jésù pé ìyẹn gan-an ni ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Látìgbà náà wá, a kò tún nílò ẹbọ mìíràn mọ́. Títí gbére ni ẹbọ Jésù yóò máa báṣẹ́ lọ.—Jòhánù 14:6; Kólósè 2:13, 14; Hébérù 9:11-14, 24.
18. Irú ẹgbẹ́ àlùfáà wo ni Ísírẹ́lì Ọlọ́run para pọ̀ jẹ́, kí sì ni iṣẹ́ tí wọ́n gbà?
18 Báwo wá ni àwọn tí í ṣe Ísírẹ́lì Ọlọ́run ṣe jẹ́ “àlùfáà Jèhófà”? Nígbà tí Pétérù ń kọ̀wé sí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró, ó ní: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá’ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pétérù 2:9) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà tó gba iṣẹ́ pàtó kan, ìyẹn ni pé: kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ nípa ògo Jèhófà fún àwọn orílẹ̀-èdè. Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni wọ́n ní láti jẹ́. (Aísáyà 43:10-12) Ní gbogbo àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, iṣẹ́ pàtàkì yìí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi àìyẹhùn gbájú mọ́ lójú méjèèjì. Ìyẹn sì mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn wá dara pọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu iṣẹ́ jíjẹ́rìí nípa Ìjọba Jèhófà yìí.
19. Iṣẹ́ wo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò láǹfààní láti ṣe?
19 Síwájú sí i, àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run ní ìrètí pé àwọn yóò ṣe iṣẹ́ àlùfáà ní ọ̀nà mìíràn. Bí wọ́n bá ti kú, a óò jí wọn dìde sí ìyè àìleèkú ní ọ̀run. Yàtọ̀ sí pé wọn yóò bá Jésù jọba nínú Ìjọba rẹ̀ níbẹ̀, wọn yóò tún jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run. (Ìṣípayá 5:10; 20:6) Nípa bẹ́ẹ̀, wọn yóò láǹfààní láti lo àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù fún àwọn ọmọ aráyé olóòótọ́ tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Nínú ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, èyí tó wà nínú Ìṣípayá orí kejìlélógún, wọ́n tún ṣàpèjúwe wọn níbẹ̀ pé wọ́n jẹ́ “àwọn igi.” Gbogbo “àwọn igi” yìí, tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, ni ó sì rí ní ọ̀run, tí wọ́n “ń mú irè oko méjìlá ti èso jáde . . . tí ń so àwọn èso wọn ní oṣooṣù. Ewé àwọn igi náà sì wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.” (Ìṣípayá 22:1, 2) Áà, iṣẹ́ àlùfáà tí wọn yóò ṣe yìí ga lọ́lá o!
-
-
Òdodo Rú Jáde ní SíónìÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
a Ó ṣeé ṣe kí Aísáyà 61:5 ṣẹ láyé àtijọ́, nítorí àwọn tí kì í ṣe Júù àbínibí bá àwọn Júù àbínibí padà wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ṣèrànwọ́ láti mú ilẹ̀ náà padà bọ̀ sípò. (Ẹ́sírà 2:43-58) Àmọ́, ó jọ pé kìkì àwọn Ísírẹ́lì Ọlọ́run ni ẹsẹ kẹfà síwájú kàn.
-