“Gẹ́gẹ́ Bí Ọjọ́ Igi”
NÍ OHUN tí ó lé ní ẹgbẹ̀ta ọdún sẹ́yìn, Mose kọ̀wé pé: “Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wa; bí ó si ṣe pé nipa ti agbára, bí wọ́n bá tó ọgọ́rin ọdún, agbára wọn làálàá òun ìbìnújẹ́ ni.”—Orin Dafidi 90:10.
Láìka ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀-ìṣègùn sí, gígùn ìwàláàyè ènìyàn ṣì wà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nígbà ayé Mose. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò ní kọ aráyé tì sínú ipò ìwàláàyè tí kò tọ́jọ́ yìí. Nínú ìwé Isaiah nínú Bibeli, Ọlọrun wí pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi rí, àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”—Isaiah 65:22.
Ọ̀kan lára àwọn igi tí ìwàláàyè rẹ̀ tọ́jọ́ jùlọ ní àwọn ilẹ̀ Bibeli ni igi ólífì. Igi tí a yàwòrán rẹ̀ síhìn-ín jẹ́ ọ̀kan lára àwọn igi ólífì tí wọ́n ti wàláàyè fún ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí wọ́n sì tún ń gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní Galili. Nígbà wo ni àwọn ẹ̀dá ènìyàn yóò tó lè wàláàyè pẹ́ tóbẹ́ẹ̀? Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ṣàlàyé pé yóò jẹ́ nígbà tí Ọlọrun bá dá “ọ̀run titun àti ayé titun.”—Isaiah 65:17.
Bákan náà ìwé Ìṣípayá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa fífìdí “ọ̀run titun kan ati ilẹ́-ayé titun kan” múlẹ̀—àkóso titun ní ọ̀run àti ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn titun nígbà tí Ọlọrun ‘bá nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, tí ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́.’—Ìṣípayá 21:1, 4, NW.
Ìlérí Ọlọrun yìí yóò ni ìmúṣẹ láìpẹ́. Nígbà náà, ọjọ́ igi ólífì pàápàá yóò dàbí kìkì wákàtí 24. Àwa yóò sì ní àkókò tí ó pọ̀ tó láti gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wa dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.