-
‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
29. (a) Kí ni ohun ìdùnnú tí àwọn onígbọràn lára àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò rí gbà ní ilẹ̀ Júdà tó padà bọ̀ sípò? (b) Kí nìdí tí igi fi jẹ́ ohun tó bá a mu láti fi ṣàpèjúwe ẹ̀mí gígùn? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
29 Jèhófà ń bá àpèjúwe rẹ̀ lọ nípa bí nǹkan yóò ṣe rí ní ilẹ̀ Júdà tó padà bọ̀ sípò, ó ní: “Wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Aísáyà 65:21, 22) Lẹ́yìn tí àwọn onígbọràn lára àwọn èèyàn Ọlọ́run bá padà dé ilẹ̀ Júdà tó dahoro, èyí tó dájú pé kò ní ní ilé àti ọgbà àjàrà nínú, yóò jẹ́ ìdùnnú fún wọn láti máa gbé nínú ilé tiwọn, kí wọ́n sì máa jẹ èso ọgbà àjàrà tiwọn. Ọlọ́run yóò bù kún iṣẹ́ ọwọ́ wọn, ẹ̀mí wọn yóò sì gùn, àní bí ọjọ́ igi, tí wọ́n ó fi lè máa jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn nìṣó.e
30. Ipò ìdùnnú wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wà lóde òní, kí ni wọn yóò sì gbádùn nínú ayé tuntun?
30 Láyé ìgbà tiwa yìí, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ṣẹ lọ́nà kan. Àwọn èèyàn Jèhófà jáde wá látinú ìgbèkùn tẹ̀mí lọ́dún 1919, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú “ilẹ̀” wọn, tàbí àgbègbè ìgbòkègbodò àti ìjọsìn wọn padà bọ̀ sípò. Wọ́n fi àwọn ìjọ lọ́lẹ̀, wọ́n sì dẹni tó ń so èso nípa tẹ̀mí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, nísinsìnyí pàápàá, àwọn èèyàn Jèhófà ń gbádùn párádísè nípa tẹ̀mí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Kí ó dá wa lójú pé irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀ yóò máa bá a lọ ni títí wọnú Párádísè tí ó ṣeé fojú rí. Bí a bá tiẹ̀ ní ká fojú inú wo ohun tí Jèhófà yóò tipasẹ̀ ọwọ́ àti ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùyọ̀ǹda ara ẹni gbé ṣe nínú ayé tuntun, a kò lè róye rẹ̀ tán. Áà, ìdùnnú tó kọyọyọ ni yóò jẹ́ láti kọ́ ilé tìrẹ kí o sì máa wá gbé inú rẹ̀! Iṣẹ́ tó ń mú inú ẹni dùn yóò sì pọ̀ jaburata lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Èrè ńlá mà ni yóò jẹ o láti máa “rí ohun rere” nígbà gbogbo látinú iṣẹ́ àṣekára rẹ! (Oníwàásù 3:13) Ṣé àkókò á sì gùn tó fún wa láti fi lè gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wa dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́? Yóò gùn tó dájúdájú! Ẹ̀mí gígùn kánrin táwọn èèyàn olóòótọ́ yóò ní yóò gùn “bí ọjọ́ igi,” àní yóò tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún yóò sì jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá!
-
-
‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
e Igi jẹ́ ohun tó bá a mu láti fi ṣàpèjúwe ẹ̀mí gígùn, nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára ohun alààyè tí a mọ̀ pé ó máa ń pẹ́ jù lọ kí ó tó kú. Bí àpẹẹrẹ, igi ólífì lè máa so èso nìṣó fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, ó sì lè lò tó ẹgbẹ̀rún ọdún láìkú.
-