ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Jọ̀wọ́ Jẹ́ Ká Pa Dà Wá Sílé”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | April 1
    • “Dájúdájú, Èmi Yóò Ṣe Ojú Àánú sí I”

      Jèhófà fẹ́ràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ó ní: “Mo ti di Baba fún Ísírẹ́lì; ní ti Éfúráímù, òun ni àkọ́bí mi.” (Jeremáyà 31:9) Ǹjẹ́ bàbá kan tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ kò ní tẹ́wọ́ gba ọmọ rẹ̀ tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn pa dà? Wo bí Jèhófà ṣe sọ ìyọ́nú tó ní sí àwọn èèyàn rẹ̀ bí bàbá ṣe ń yọ́nú sí ọmọ.

      “Ọmọ àtàtà ha ni Éfúráímù jẹ́ sí mi, tàbí ọmọ tí a hùwà sí lọ́nà ìfẹ́ni? Nítorí dé àyè tí mo sọ̀rọ̀ lòdì sí i dé, láìkùnà, èmi yóò rántí rẹ̀ síwájú sí i.” (Ẹsẹ 20) Ọ̀rọ̀ ìyọ́nú tó ga mà lọ̀rọ̀ yìí o! Gẹ́gẹ́ bí òbí onífẹ̀ẹ́ kan tí kò gbàgbàkugbà, Ọlọ́run rí i pé òun ní láti sọ̀rọ̀ “lòdì sí” àwọn ọmọ òun yìí, ó sì kìlọ̀ fún wọn lemọ́lemọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nígbà tí wọ́n sì kọ etí ikún sí i, ó jẹ́ kí wọ́n kó wọn lọ sí ìgbèkùn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí wọ́n kúrò nílé. Àmọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ wọ́n níyà, kò gbàgbé wọn. Kò lè gbàgbé wọn láéláé. Bàbá onífẹ̀ẹ́ kan kì í gbàgbé àwọn ọmọ rẹ̀. Àmọ́ báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tó rí i pé àwọn ọmọ rẹ̀ yìí ronú pìwà dà tọkàntọkàn?

      “Ìfun mi . . . di èyí tí ó ru gùdù fún un.b Dájúdájú, èmi yóò ṣe ojú àánú sí i.” (Ẹsẹ 20) Ọkàn Jèhófà fà sí àwọn ọmọ rẹ̀ gidigidi. Bí wọ́n ṣe ronú pìwà dà tọkàntọkàn dùn mọ́ Jèhófà gan-an, ó sì ń wù ú gan-an pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Bí àánú ti ṣe bàbá tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àkàwé ọmọ onínàákúnàá yẹn náà ni ‘àánú ṣe’ Jèhófà, ó sì ń hára gàgà láti gba àwọn ọmọ rẹ̀ pa dà sílé.—Lúùkù 15:20.

      “Jèhófà, Jọ̀wọ́ Jẹ́ Kí N Pa Dà Wá Sílé”

      Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jeremáyà 31:18-20 jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti àánú Jèhófà. Ọlọ́run kò gbàgbé àwọn tó ti ń sìn ín nígbà kan rí. Tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ láti pa dà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ńkọ́? Ọlọ́run “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Ọlọ́run kò ní ṣàì tẹ́wọ́ gba àwọn tí wọ́n ronú pìwà dà tọkàntọkàn tí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. (Sáàmù 51:17) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni inú rẹ̀ máa ń dùn láti gbà wọ́n pa dà sílé, ìyẹn inú ètò rẹ̀.—Lúùkù 15:22-24.

  • “Jọ̀wọ́ Jẹ́ Ká Pa Dà Wá Sílé”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | April 1
    • b Nígbà tí ìwé kan tó jẹ́ ìwé atọ́nà fún àwọn atúmọ̀ Bíbélì ń ṣàlàyé àpèjúwe ìfun tó ru gùdù yìí, ó ní: “Àwọn Júù gbà pé inú èèyàn lọ́hùn-ún ni èèyàn ti máa ń mọ nǹkan lára jù.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́