ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Jọ̀wọ́, Ṣègbọràn Sí Ohùn Jèhófà”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
    • 12. Kí làwọn alàgbà ní láti ṣe nígbà míì láti dáàbò bo ìjọ?

      12 Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló tẹ́ńbẹ́lú ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń gbìyànjú léraléra láti ṣe fún wọn nípasẹ̀ Jeremáyà. Lónìí bákan náà, ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lè má ronú pìwà dà, kó wá kọ ìrànlọ́wọ́ táwọn alàgbà fẹ́ ṣe fún un. Nírú ipò bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà ní láti ṣe ohun tí Bíbélì sọ, kí wọ́n yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ náà lẹ́gbẹ́ láti dáàbò bo ìjọ. (1 Kọ́r. 5:11-13; wo àpótí tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Wọ́n Wà Láìsí Òfin,” lójú ìwé 73.) Àmọ́ ṣé ó wá túmọ̀ sí pé kò sírètí fún onítọ̀hún mọ́ ni, pé kò lè rí ojú rere Jèhófà mọ́ láéláé? Rárá o. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ya ọlọ̀tẹ̀ fún ìgbà pípẹ́; síbẹ̀ Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ padà, ẹ̀yin ọ̀dàlẹ̀ ọmọ. Èmi yóò mú ipò ìwà ọ̀dàlẹ̀ yín lára dá.” (Jer. 3:22)a Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ní kí àwọn oníwà àìtọ́ pa dà sọ́dọ̀ òun. Ńṣe ló tiẹ̀ dìídì fún wọn nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.

      WỌ́N WÀ LÁÌSÍ ÒFIN

      Irú ìgbésí ayé wo làwọn Júù ń gbé lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù? Jeremáyà ṣàpèjúwe rẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan nínú ìwé Ìdárò 2:9. Ó ní wọ́n ti wó àwọn odi ìlú náà, bóyá títí kan àwọn ẹnubodè tí wọ́n fi dáàbò bò ó tẹ́lẹ̀. Àmọ́ èyí tó burú jù ni pé “kò sí òfin.” Ṣé ohun tí Jeremáyà wá ń sọ ni pé ìwà tani-yóò-mú-mi gbòde kan láàárín àwọn Júù tó ṣẹ́ kù ní Júdà? Rárá o. Ó jọ pé ohun tó ń sọ ni pé kò sí ààbò àti ìtùnú tẹ̀mí mọ́ èyí táwọn Júù ní tẹ́lẹ̀ nígbà táwọn àlùfáà àtàwọn wòlíì olóòótọ́ ń kọ́ wọn ní Òfin Ọlọ́run. Àwọn wòlíì èké tó ń bá wọn sọ̀rọ̀ kò rí “ìran” tòótọ́, ìtọ́ni látọ̀dọ̀ Jèhófà kọ́ ni wọ́n ń sọ fún wọn. “Ìran” ohun tí kò ní láárí ni wọ́n ń rí.—Ìdárò 2:14.

      Ẹni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ Ọlọ́run náà lè rí i pé irú ipò bẹ́ẹ̀ lòun wà. Kò ní rí ìfararora aláyọ̀ tó ti ń gbádùn tẹ́lẹ̀ láàárín àwọn ará mọ́, títí kan àbójútó onífẹ̀ẹ́ tó ń rí látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà. Kò ní rí àwọn ìtọ́ni tó ṣe kókó tó ti ń rí tẹ́lẹ̀ gbà mọ́. Ó ṣeé ṣe kó wá rí i pé nǹkan ńlá lòun ń pàdánù nínú ayé tóun wà níbi tí ‘kò ti sí òfin’ látọ̀dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ ṣá, ó ṣì lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà kó rí ojú rere rẹ̀, kó sì tún máa rí ìbùkún rẹpẹtẹ gbà. (2 Kọ́r. 2:6-10) Láìsí àní-àní, wàá gbà pé ṣíṣègbọràn sí Jèhófà, kéèyàn má sì wà láìsí òfin ló ti dára jù.

  • “Jọ̀wọ́, Ṣègbọràn Sí Ohùn Jèhófà”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
    • a Ìjọba Ísírẹ́lì tó wà níhà àríwá ni Jèhófà ń bá wí níbí. Àwọn èèyàn ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá yìí ti wà nígbèkùn fún odindi ọgọ́rùn-ún ọdún nígbà tí Jeremáyà jíṣẹ́ yìí fún wọn. Jeremáyà sì sọ pé títí di bóun ṣe ń jíṣẹ́ yẹn, orílẹ̀-èdè yẹn lápapọ̀ ò tíì ronú pìwà dà. (2 Ọba 17:16-18, 24, 34, 35) Àmọ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lè pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì rí ojú rere rẹ̀ bóyá kí wọ́n tiẹ̀ kúrò nígbèkùn pàápàá.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́