ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bárúkù Akọ̀wé Jeremáyà Tó Dúró Tì Í Gbágbáágbá
    Ilé Ìṣọ́—2006 | August 15
    • Má Ṣe Wá “Àwọn Ohun Ńláńlá”

      Ìgbà kan wà tí ìbànújẹ́ bá Bárúkù lákòókò tó ń kọ àkájọ ìwé àkọ́kọ́. Ó sọ pé: “Mo gbé wàyí, nítorí pé Jèhófà ti fi ẹ̀dùn-ọkàn kún ìrora mi! Agara ti dá mi nítorí ìmí ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ibi ìsinmi kankan.” Kí ló mú kí ìbànújẹ́ bá Bárúkù?—Jeremáyà 45:1-3.

      Bíbélì kò sọ ní pàtó. Ṣùgbọ́n, ìwọ náà gbìyànjú láti fojú inú wo ipò tí Bárúkù wà. Bó ṣe ń ṣàkọsílẹ̀ ìkìlọ̀ tí Jèhófà ti ń fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà láti ọdún mẹ́tàlélógún sẹ́yìn á ti jẹ́ kó rí i kedere bí àwọn èèyàn náà ṣe fi ìjọsìn Jèhófà sílẹ̀ àti bí wọ́n ṣe kọ Jèhófà sílẹ̀. Bí Jèhófà sì ṣe sọ pé òun máa pa Jerúsálẹ́mù àti Júdà run, tí òun yóò sì jẹ́ káwọn ará Bábílónì kó àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè náà lọ sígbèkùn fún àádọ́rin ọdún yóò ti kó ìbànújẹ́ bá a. Ọdún tí Bárúkù kọ àkájọ ìwé àkọ́kọ́ yẹn ni Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ yẹn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà yẹn náà ni Bárúkù kọ ọ́ sínú àkájọ ìwé náà. (Jeremáyà 25:1-11) Ìyẹn nìkan kọ́ o, ohun mìíràn tó tún lè kó ìbànújẹ́ bá a ni pé, bó ṣe dúró ti Jeremáyà gbágbáágbá nígbà tí gbogbo nǹkan le koko yìí lè jẹ́ kí wọ́n yọ ọ́ kúrò nípò tó wà kí iṣẹ́ sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

      Èyí ó wù kó jẹ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ bá Bárúkù sọ̀rọ̀ kó lè fi ìdájọ́ Ọlọ́run tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sọ́kàn. Jèhófà ní: “Ohun ti mo kọ́ ni èmi yóò ya lulẹ̀, ohun tí mo sì gbìn ni èmi yóò fà tu, àní gbogbo ilẹ̀ náà.” Ó wá gba Bárúkù lámọ̀ràn pé: “Ṣùgbọ́n ní tìrẹ, ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.”—Jeremáyà 45:4, 5.

      Jèhófà kò sọ ohun tí “àwọn ohun ńláńlá” wọ̀nyí jẹ́, àmọ́ Bárúkù yóò mọ̀ lọ́kàn ara rẹ̀ bóyá ipò ọlá lòun ń lépa tàbí òun fẹ́ di gbajúmọ̀ tàbí ọlọ́rọ̀. Jèhófà gbà á nímọ̀ràn pé kó má hùwà òmùgọ̀, kó má sì gbàgbé ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Jèhófà sọ pé: “Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí gbogbo ẹran ara, . . . èmi yóò sì fi ọkàn rẹ fún ọ bí ohun ìfiṣèjẹ ní gbogbo ibi tí ìwọ bá lọ.” Ohun tó ṣeyebíye jù lọ fún Bárúkù ni ẹ̀mí rẹ̀, èyí sì ni ohun tí Ọlọ́run máa pa mọ́ níbikíbi tí ì báà lọ.—Jeremáyà 45:5.

  • Bárúkù Akọ̀wé Jeremáyà Tó Dúró Tì Í Gbágbáágbá
    Ilé Ìṣọ́—2006 | August 15
    • Nígbà tí Jèhófà ní kí Jeremáyà sọ fún Bárúkù pé ìgbà yẹn kọ́ ló yẹ kó máa kó “àwọn ohun ńláńlá” jọ ní àwọn ọjọ́ tó gbẹ̀yìn ìjọba Júdà, kò sí àní-àní pé ó ṣègbọràn, nítorí pé Jèhófà dá ẹ̀mí rẹ̀ sí. Á dára káwa náà tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí o, torí pé àwọn ọjọ́ tó kẹ́yìn ètò àwọn nǹkan yìí la wà. Bí Jèhófà ṣe ṣèlérí fún Bárúkù pé òun máa dá ẹ̀mí rẹ̀ sí ló ṣe ṣèlérí pé òun máa dá ẹ̀mí tiwa náà sí. Bíi ti Bárúkù, ǹjẹ́ kò yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́