-
Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti Mọ Jèhófà?Ilé Ìṣọ́—2013 | March 15
-
-
8, 9. Nígbà ayé Jeremáyà, kí ló wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù? Kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe?
8 Ọlọ́run sọ ohun tí àwọn Júù yẹn gbọ́dọ̀ ṣe fún wọn. Ohun tó sọ fún wọn yẹn sì wá jẹ́ ká lóye ìdí tó fi pè wọ́n ní “aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà.” Jèhófà sọ fún wọn pé kí wọ́n mú ìwà búburú kúrò nínú ọkàn wọn. Lẹ́yìn náà, ó ṣàlàyé ìdí tó fi fẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Kí ìhónú mi má bàa jáde lọ . . . ní tìtorí búburú ìbálò yín.” Èyí jẹ́ ká rí i pé ohun tó mú kí wọ́n máa ṣàìgbọràn sí Jèhófà ni pé ohun búburú ló wà lọ́kàn wọn. (Ka Máàkù 7:20-23.) Wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀, wọ́n sì kọ̀ láti yí pa dà. Èrò ọkàn wọn àti ìwà wọn burú lójú Jèhófà. (Ka Jeremáyà 5:23, 24; 7:24-26.) Ọlọ́run sọ bí wọ́n ṣe lè yí pa dà fún wọn, ó ní: “Ẹ dá ara yín ládọ̀dọ́ fún Jèhófà, kí ẹ sì gé adọ̀dọ́ ọkàn-àyà yín kúrò.”—Jer. 4:4; 18:11, 12.
9 Ńṣe lọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Jeremáyà dà bí ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, tí wọ́n sì ní láti ṣiṣẹ́ abẹ fún. Irú ìṣòro táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní nígbà ayé Mósè náà nìyẹn. (Diu. 10:16; 30:6) Báwo làwọn Júù ṣe lè “gé adọ̀dọ́ ọkàn-àyà” wọn “kúrò”? Ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n mú èrò tàbí ìfẹ́ ọkàn èyíkéyìí tó ń mú kí wọn ṣá òfin Jèhófà tì kúrò nínú ọkàn wọn.—Ìṣe 7:51.
-
-
Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti Mọ Jèhófà?Ilé Ìṣọ́—2013 | March 15
-
-
11, 12. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn wa? (b) Kí la ò gbọ́dọ̀ retí pé kí Jèhófà ṣe?
11 Jèhófà fẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa mọ òun. Lédè mìíràn, ó fẹ́ ká jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ òun, kò sì fẹ́ kí ohunkóhun fà wá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Jeremáyà sọ pé Jèhófà máa ń wádìí àwọn olódodo wò àti pé ó ń rí “kíndìnrín àti ọkàn-àyà.” (Jer. 20:12) Bí Jèhófà bá ń ṣàyẹ̀wò ọkàn àwọn tó jẹ́ olódodo, ǹjẹ́ kò ní dára kí gbogbo wa ṣàyẹ̀wò ọkàn wa ká lè mọ ohun tó wà níbẹ̀ gan-an? (Ka Sáàmù 11:5.) Tá a bá fi òótọ́ inú ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn wa, ó ṣeé ṣe ká rí i pé àwọn èrò tí kò tọ́ ti fara pa mọ́ síbẹ̀. A lè rí i pé a ti ń ní àwọn àfojúsùn kan tí kò dára àti pé ìwà wa àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa ń fẹ́ àbójútó. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe la máa ń lọ́ra láti ṣègbọràn sí Jèhófà. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ńṣe lọ̀rọ̀ wa dà bíi tẹni tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ abẹ fún kí ọkàn rẹ̀ lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Iṣẹ́ abẹ ìṣàpẹẹrẹ yìí ló máa jẹ́ ká mú àwọn ohun búburú yẹn kúrò lọ́kàn wa. Kí wá ni díẹ̀ lára àwọn ìwà tàbí ìmọ̀lára tí kò tọ́ tó ṣeé ṣe kó wà nínú ọkàn wa? Kí la lè ṣe nípa irú àwọn ìwà tàbí ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀?—Jer. 4:4.
-