-
“Kí O sì Sọ Ọ̀rọ̀ Yìí Fún Wọn”Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
-
-
‘JÈHÓFÀ FỌWỌ́ KAN ẸNU MI’
3. Kí ni Ọlọ́run ṣe fún Jeremáyà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wòlíì, ipa wo sì ni èyí ní lórí rẹ̀?
3 Rántí pé nígbà tí Jeremáyà di wòlíì, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí: “Ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí èmi yóò rán ọ lọ ni kí o lọ; ohun gbogbo tí mo bá sì pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ. Má fòyà nítorí ojú wọn, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè,’ ni àsọjáde Jèhófà.” (Jer. 1:7, 8) Ọlọ́run sì ṣe ohun kan tí Jeremáyà kò rò tẹ́lẹ̀. Jeremáyà sọ pé: “Jèhófà na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú kí ó kan ẹnu mi. Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún mi pé: ‘Kíyè sí i, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ. Wò ó, mo ti fàṣẹ yàn ọ́ lónìí.’” (Jer. 1:9, 10) Látìgbà yẹn ni Jeremáyà ti mọ̀ pé òun ti di agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run Olódùmarè.a Ọlọ́run sì ti Jeremáyà lẹ́yìn gan-an débi pé ìtara rẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i.—Aísá. 6:5-8.
4. Sọ àpẹẹrẹ àwọn onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó o mọ̀.
4 Lónìí, Jèhófà kì í fọwọ́ ara rẹ̀ kan èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe ṣe fún Jeremáyà níhìn-ín. Síbẹ̀, ó ń jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ mú kó máa wù wọ́n láti wàásù ìhìn rere. Púpọ̀ nínú wọn sì ní ìtara gan-an. Àpẹẹrẹ kan ni ti Maruja tó ń gbé nílẹ̀ Sípéènì. Ó lé ní ogójì ọdún tó ti rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀. Èyí mú kó ṣòro fún un láti máa wàásù láti ilé dé ilé. Nítorí náà, ó wá àwọn ọ̀nà mìíràn táá fi lè máa ṣe déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀nà kan ni pé ó máa ń kọ lẹ́tà. Maruja máa ń sọ ohun tó fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ fún ọmọbìnrin rẹ̀. Ọmọ yìí á wá kọ wọ́n sínú lẹ́tà. Ní oṣù kan tí Maruja àti ọmọbìnrin rẹ̀ tó ń bá a kọ lẹ́tà yìí ṣe iṣẹ́ ìwàásù lákànṣe, wọ́n fi lẹ́tà tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [150] ránṣẹ́ sáwọn èèyàn, wọ́n sì fi àṣàrò kúkúrú sínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ìsapá wọn yìí ti mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń gbé lábúlé kan tó wà nítòsí wọn láti gbọ́ ìhìn rere. Maruja sọ fún ọmọ rẹ̀ pé: “Tí ọ̀kan nínú àwọn lẹ́tà wa bá bọ́ sọ́wọ́ ẹni tó lọ́kàn tó dáa, Jèhófà á jẹ́ kó yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Alàgbà kan ní ìjọ tí Maruja wà sọ pé: “Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí irú àwọn arábìnrin bíi Maruja, tó máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́.”
-
-
“Kí O sì Sọ Ọ̀rọ̀ Yìí Fún Wọn”Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
-
-
a Jèhófà sábà máa ń mú kí áńgẹ́lì wá ṣojú fún òun bíi pé òun gan-an ló ń sọ̀rọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ṣe níhìn-ín.—Oníd. 13:15, 22; Gál. 3:19.
-