Gbígbé Àjàgà Nígbà Èwe
NÍ “ÀWỌN àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” wọ̀nyí, àwọn èwe ń dojú kọ pákáǹleke ńláǹlà. (2 Tímótì 3:1) Ojoojúmọ́ ni àwọn ìsọfúnni tí ń fún ìwà pálapàla, sìgá mímu, àti àwọn ìwà tí ń ṣekú pani mìíràn níṣìírí ń gbéjà kò wọ́n. Àwọn kan lè máa yọ ṣùtì sí àwọn tí ń tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì nítorí tí wọ́n kọ̀ láti tẹ̀ sí ibi tí ayé tẹ̀ sí, àwọn Kristẹni kan sì lè rò pé ì bá sàn jù bí àwọn bá kúkú juwọ́ sílẹ̀.
Nígbà tí ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa ń parí lọ, Jeremáyà kọ̀wé pé: “Ó dára kí abarapá ọkùnrin ru àjàgà ní ìgbà èwe rẹ̀.” (Ìdárò 3:27) Kí ni ó ní lọ́kàn? Pé kíkọ́ láti kojú àwọn àdánwò nígbà èwe ń mú kí a gbára dì láti kojú ìpèníjà tí a óò bá pàdé nígbà tí a bá dàgbà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pákáǹleke kì í ṣe ohun tí ń gbádùn mọ́ni, síbẹ̀ àwọn èwe àti àgbà Kristẹni kò lè yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. (2 Tímótì 3:12) Ṣùgbọ́n àǹfààní ìṣòtítọ́ pọ̀ ju ìgbádùn ìgbà díẹ̀ tí jíjuwọ́sílẹ̀ lè mú wá lọ.
Bí o bá jẹ́ èwe, gbéjà ko ìdánwò ìgbàgbọ́ lójú méjèèjì. Nígbà tí a bá dán ọ wò láti lọ́wọ́ nínú ìwà àìtọ́, kọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè nira láti ṣe èyí lọ́wọ́lọ́wọ́, lẹ́yìnwá ọ̀la, àníyàn tí ìwọ yóò ní yóò mọ níwọ̀nba. Jésù ṣèlérí pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín . . . , ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:29, 30.
Tẹ́wọ́ gba ìpèníjà gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò fún ọ ní ìgbésí ayé tí ó dára jù lọ nísinsìnyí àti ìrètí tí ó dájú fún ọjọ́ ọ̀la. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.