-
‘Mo Rí Ìran Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run’Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
15. Kí ni Ìsíkíẹ́lì sọ nípa bí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ṣe rí àti bí wọ́n ṣe tóbi tó?
15 Bí àwọn àgbà kẹ̀kẹ́ náà ṣe tóbi tó ya Ìsíkíẹ́lì lẹ́nu gan-an. Ó ní: “Àwọn àgbá náà ga débi pé wọ́n ń bani lẹ́rù.” A lè fojú inú wo bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ń wòkè kó lè rí àwọn àgbá tó rí ràgàjì, tó ń tàn yòò, tó sì ga fíofío náà. Ó tún wá sọ nǹkan míì tó yani lẹ́nu, ó ní: “Ojú sì wà káàkiri ara àgbá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà.” Àmọ́ ohun tó jẹ́ àgbàyanu jù lọ nínú ìran yìí ni bí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ṣe jẹ́ àrà-mérìíyìírí. Ó ṣàlàyé pé: “Iṣẹ́ ara wọn àti bí wọ́n ṣe rí dà bí ìgbà tí àgbá kẹ̀kẹ́ kan wà nínú àgbá kẹ̀kẹ́ míì.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí?
-
-
‘Mo Rí Ìran Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run’Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
17 Ó dájú pé ibi tí àgbá tó ga fíofío báyìí máa yí dé tó bá yí po lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo máa lọ jìnnà gan-an. Kódà, ìran yìí fi hàn pé kẹ̀kẹ́ náà ń yára sáré bíi kíkọ mànàmáná! (Ìsík. 1:14) Yàtọ̀ síyẹn, bí àgbá náà ṣe kọjú síbi mẹ́rin lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fi hàn pé bó ṣe máa yí pa dà bìrí kọjá ohun táwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ lè ṣe. Àgbá náà lè lọ síbikíbi ní ọ̀nà èyíkéyìí láìdẹwọ́ eré tó ń sá, tí kò sì ní ṣẹ́rí pa dà! Àmọ́ kì í gba ibi tó bá rí láìmọ ohun tó ń lọ. Àwọn ojú tó wà káàkiri àwọn àgbá náà fi hàn lọ́nà tó ṣe kedere pé kẹ̀kẹ́ náà mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká rẹ̀, ní gbogbo ibi tó lè gbà.
Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà tóbi gan-an, wọ́n sì ń yára sáré lọ́nà tó kàmàmà (Wo ìpínrọ̀ 17)
-