ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Orúkọ Ìlú Náà Yóò Máa Jẹ́ Jèhófà Wà Níbẹ̀”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • 4. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àkọsílẹ̀ nípa ọrẹ sí Jèhófà?

      4 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àkọsílẹ̀ nípa ọrẹ sí Jèhófà? Bó ṣe jẹ́ pé ilẹ̀ tó jẹ́ ọrẹ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sọ́tọ̀, tí wọ́n sì wá pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà lẹ́yìn náà, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ibi tó jẹ́ ojúkò ìjọsìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà. (Ìsík. 45:1) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ làwọn tó wà nígbèkùn yìí kọ́ látinú bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ pínpín ilẹ̀ náà láti ibi tó ṣe pàtàkì jù. Ìjọsìn Jèhófà ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi sípò àkọ́kọ́ láyé wọn. Bákan náà lónìí, àwọn nǹkan tẹ̀mí, irú bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wíwá sáwọn ìpàdé Kristẹni àti kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù la kà sí pàtàkì jù. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe fi ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́, àá lè máa fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo lójoojúmọ́ ayé wa.

  • “Ilẹ̀ Tí Ẹ Ó Yà Sọ́tọ̀ Láti Fi Ṣe Ọrẹ”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • E. “Ilẹ̀ [Tàbí Ọrẹ] Mímọ́”

      Wọ́n tún pè é ní ‘ìpín tó jẹ́ mímọ́.’ Ibi tó wà lápá òkè ilẹ̀ náà jẹ́ ti “àwọn ọmọ Léfì.” “Ohun mímọ́” ló jẹ́. “Ilẹ̀ mímọ́ tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà” ló wà ní àárín. “Ibẹ̀ ni ilé wọn máa wà, ibẹ̀ ló sì máa jẹ́ ibi mímọ́” tàbí tẹ́ńpìlì.

      ÌSÍK. 45:​1-5; 48:​9-14

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́