ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Wo Ni “Ẹ̀dá Alààyè Tó Ní Ojú Mẹ́rin Náà”?
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • 15. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Ìsíkíẹ́lì kọ́ nínú ìran tó kọ́kọ́ rí?

      15 Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì kọ́kọ́ rí yìí, ó kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan tó fi í lọ́kàn balẹ̀ nípa àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn? Ó hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó fi bẹ̀rẹ̀ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí Ìsíkíẹ́lì sọ pé òun wà ní “ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,” tó sì ń sọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó ní: “Ọwọ́ Jèhófà sì wá sórí rẹ̀ níbẹ̀.” (Ìsík. 1:3) Kíyè sí ohun tí Ìsíkíẹ́lì sọ, kò sọ pé Jerúsálẹ́mù ni òun ti rí ìran, àmọ́ ó ní níbẹ̀, ìyẹn ní Bábílónì.c Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo nìyẹn kọ́ Ìsíkíẹ́lì? Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé: Bí wọ́n tiẹ̀ mú un nígbèkùn kúrò ní Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì, wọn ò mú un kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà tàbí kúrò nínú ìjọsìn Rẹ̀. Bí Jèhófà ṣe fara han Ìsíkíẹ́lì ní Bábílónì fi hàn pé èèyàn lè ṣe ìjọsìn mímọ́ sí Ọlọ́run láìka ipò tàbí ibi tó wà sí. Bíi ti Ìsíkíẹ́lì, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ẹ̀mí tó fi ń ṣe é àti bó ṣe ń wù ú látọkàn wá pé kó sin Jèhófà.

  • Àwọn Wo Ni “Ẹ̀dá Alààyè Tó Ní Ojú Mẹ́rin Náà”?
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • c Ẹnì kan tó máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì sọ pé: Ọ̀rọ̀ yẹn “níbẹ̀” fi hàn “lọ́nà tó ṣe kedere jù lọ pé ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé . . . Ọlọ́run wà níbẹ̀ ní Bábílónì! Ìyẹn tuni nínú gan-an!”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́