ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Dáníẹ́lì—Ìwé tí Ó Dojú kọ Àyẹ̀wò Fínnífínní
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • Ọ̀RÀN ỌBA TÍ A KÒ MẸ́NU KÀN

      7. (a) Èé ṣe tí títọ́ka tí Dáníẹ́lì tọ́ka sí Bẹliṣásárì fi jẹ́ ìdùnnú àwọn olùṣelámèyítọ́ Bíbélì láti ìgbà pípẹ́ wá? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí èrò náà pé Bẹliṣásárì jẹ́ ẹni tí a dédé hùmọ̀ sínú ìtàn?

      7 Dáníẹ́lì kọ̀wé pé Bẹliṣásárì, “ọmọkùnrin” Nebukadinésárì, ní ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba ní Bábílónì nígbà tí a ṣẹ́gun ìlú ńlá náà. (Dáníẹ́lì 5:1, 11, 18, 22, 30) Láti ìgbà pípẹ́ wá ni àwọn olùṣelámèyítọ́ ti ń ta ko gbólóhùn yìí léraléra, nítorí pé kò sí ibòmíràn tí a tún ti rí orúkọ Bẹliṣásárì yàtọ̀ sí inú Bíbélì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Nábónídọ́sì, arọ́pò Nebukadinésárì, ni àwọn òpìtàn àtijọ́ sọ pé ó jọba kẹ́yìn nínú àwọn ọba Bábílónì. Nípa báyìí, ní ọdún 1850, Ferdinand Hitzig sọ pé ó dájú pé ṣe ni òǹkọ̀wé náà kàn fúnra rẹ̀ hùmọ̀ Bẹliṣásárì kan. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ èrò tí Hitzig sọ yìí kò ha dà bí ti oníwàǹwára kan lójú tìrẹ? Ó ṣe tán, àìkò mẹ́nu kan ọba yìí—pàápàá ní àsìkò kan tí a gbà pé àkọsílẹ̀ ìtàn ṣọ̀wọ́n gidigidi—ha jẹ́ ẹ̀rí pé ní tòótọ́ ni kò fìgbà kan wà rí bí? Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọdún 1854, a wú àwọn ọ̀pá alámọ̀ rìbìtì kan láti inú àwókù Úrì, ìlú ńlá ìgbàanì kan ní Bábílónì, tí ó wà ní ibi tí a ń pè ní gúúsù ilẹ̀ Iraq báyìí. Lára àwọn àkọsílẹ̀ tí Nábónídọ́sì Ọba fín sára amọ̀ wọ̀nyí ni àdúrà kan wà tí ó kọ pé fún “Bel-sar-ussur, ọmọkùnrin mi àgbà.” Kódà àwọn olùṣelámèyítọ́ wọ̀nyí gbà ni dandan, pé: Bẹliṣásárì inú ìwé Dáníẹ́lì lèyí.

      8. Báwo ni a ṣe fi hàn pé òtítọ́ ni àpèjúwe Dáníẹ́lì nípa Bẹliṣásárì pé ó jẹ́ ọba tí ń ṣàkóso?

      8 Síbẹ̀, kò tíì tẹ́ àwọn olùṣelámèyítọ́ lọ́rùn. Ọ̀kan nínú wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ H. F. Talbot sọ pé: “Èyí kò fẹ̀rí ohunkóhun múlẹ̀.” Ó ní, ọmọkùnrin tí àkọsílẹ̀ yìí sọ lè jẹ́ ọmọdé lásán, bẹ́ẹ̀, ọba tí ń ṣàkóso ni Dáníẹ́lì pè é. Ṣùgbọ́n ní ọdún kan péré lẹ́yìn tí a tẹ àkíyèsí Talbot jáde, a tún wú ọ̀pọ̀ wàláà tí a fín ọ̀rọ̀ sí jáde, tí ó tọ́ka Bẹliṣásárì pé ó ní àwọn akọ̀wé àti àwùjọ òṣìṣẹ́ agboolé. Èyí kò jẹ́ jẹ́ ọmọdé! Níkẹyìn, àwọn wàláà mìíràn dé ọ̀rọ̀ náà ládé nígbà tí wọ́n sọ pé ìgbà kan wà tí Nábónídọ́sì lọ kúrò ní Bábílónì fún ọdún mélòó kan. Àwọn wàláà wọ̀nyí tún fi hàn pé láàárín àkókò yìí, ó “fi ipò ọba” Bábílónì “síkàáwọ́” ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà (Bẹliṣásárì). Nípa bẹ́ẹ̀, ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, Bẹliṣásárì ni ọba—ajùmọ̀ṣàkóso pẹ̀lú baba rẹ̀.b

  • Dáníẹ́lì—Ìwé tí Ó Dojú kọ Àyẹ̀wò Fínnífínní
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • b Kò sí Nábónídọ́sì nílé nígbà tí Bábílónì ṣubú. Nípa báyìí, lọ́nà ẹ̀tọ́, a júwe Bẹliṣásárì gẹ́gẹ́ bí ọba ní ìgbà náà. Àwọn olùṣelámèyítọ́ ń kùn pé àwọn àkọsílẹ̀ tí kì í ṣe ti ìsìn kò pe ọba mọ́ Bẹliṣásárì gẹ́gẹ́ bí orúkọ oyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ẹ̀rí tí ó jẹ́ ti ìgbàanì fi hàn pé àwọn ará ìgbà yẹn tilẹ̀ lè pe gómìnà pàápàá ní ọba.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́