-
A Gbà Á Sílẹ̀ Lẹ́nu Àwọn Kìnnìún!Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
-
-
20. Kí ni ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọ̀tá Dáníẹ́lì tí wọ́n ṣe kèéta rẹ̀?
20 Nísinsìnyí tí Dáníẹ́lì ti bọ́ nínú ewu, ọ̀ràn mìíràn ń bẹ nílẹ̀ fún Dáríúsì láti bójú tó. “Ọba . . . pàṣẹ, wọ́n sì mú àwọn abarapá ọkùnrin tí ó fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì wá, wọ́n sì sọ wọ́n sínú ihò kìnnìún, àwọn ọmọ wọn àti àwọn aya wọn; wọn kò sì tíì dé ìsàlẹ̀ ihò náà kí àwọn kìnnìún náà tó kápá wọn, gbogbo egungun wọn ni wọ́n sì fọ́ túútúú.”d—Dáníẹ́lì 6:24.
21. Ní ti ọ̀nà ìgbàhùwà sí àwọn mẹ́ńbà ìdílé àwọn tí ó bá ṣe ohun tí kò tọ́, ìyàtọ̀ wo ni ó wà nínú Òfin Mósè àti òfin àwọn àwùjọ kan nígbàanì?
21 Pípa tí a pa àwọn onítẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun náà tayatọmọ, láìpa kìkì àwọn nìkan, lè dà bí èyí tí ó ti le koko jù. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, Òfin tí Ọlọ́run pèsè nípasẹ̀ wòlíì Mósè sọ pé: “Kí a má ṣe fi ikú pa àwọn baba ní tìtorí àwọn ọmọ, kí a má sì fi ikú pa àwọn ọmọ ní tìtorí àwọn baba. Kí a fi ikú pa olúkúlùkù nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀.” (Diutarónómì 24:16) Àmọ́ ṣá, nínú àwọn àwùjọ kan nígbàanì, bí ẹnì kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wúwo, kì í ṣe ohun tí ó ṣàjèjì pé kí a pa àwọn mẹ́ńbà ìdílé ẹni tí ó ṣàìtọ́ náà pa pọ̀ mọ́ ọn. Bóyá kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé yẹn má bàa gbẹ̀san lọ́jọ́ iwájú ni a ṣe ń ṣe èyí. Àmọ́, Dáníẹ́lì kọ́ ló fa ohun tí a ṣe sí ìdílé àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ wọ̀nyẹn. Ó ṣeé ṣe kí àjálù tí àwọn ẹni burúkú wọ̀nyẹn fà bá ìdílé wọn tilẹ̀ bà á nínú jẹ́.
-
-
A Gbà Á Sílẹ̀ Lẹ́nu Àwọn Kìnnìún!Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
-
-
d A fi ọ̀rọ̀ náà, “fẹ̀sùn kan,” túmọ̀ gbólóhùn èdè Árámáíkì kan tí a tún lè túmọ̀ sí “bani jẹ́.” Èyí gbé ète ibi tí àwọn ọ̀tá Dáníẹ́lì ní yọ.
-