ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ta ní lè Dìde sí Olórí Àwọn Ọmọ Aládé?
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • 13. Kí ní hù láti inú ọ̀kan lára ìwo mẹ́rin náà, báwo ni ó sì ṣe gbé ìgbésẹ̀?

      13 Ìmúṣẹ apá tí ó tẹ̀ le nínú ìran náà gbà ju ẹgbọ̀kànlá [2,200] ọdún lọ, ó nasẹ̀ dé àkókò òde òní. Dáníẹ́lì kọ̀wé pé: “Láti inú ọ̀kan lára wọn [ìwo mẹ́rin náà] . . . ni ìwo mìíràn ti jáde wá, ọ̀kan tí ó kéré, ó sì ń tóbi sí i gidigidi síhà gúúsù àti síhà yíyọ oòrùn àti síhà Ìṣelóge. Ó sì tóbi sí i dé iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run, tí ó fi mú àwọn kan lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn kan lára ìràwọ̀ já bọ́ sí ilẹ̀, ó sì ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. Àti dé iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ Olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni ó gbé àgbéré ńláǹlà, a sì mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, a sì wó ibi àfìdímúlẹ̀ ibùjọsìn rẹ̀ lulẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan ni a fi léni lọ́wọ́, pa pọ̀ pẹ̀lú apá pàtàkì ìgbà gbogbo, nítorí ìrélànàkọjá; ó sì ń bá a lọ láti wó òtítọ́ mọ́lẹ̀, ó gbé ìgbésẹ̀, ó sì kẹ́sẹ járí.”—Dáníẹ́lì 8:9-12.

      14. Kí ni áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ nípa ìgbòkègbodò ìwo kékeré ìṣàpẹẹrẹ náà, kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ sí ìwo náà?

      14 Kí a tó lè lóye àwọn ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fà yọ yìí, a ní láti fetí sí áńgẹ́lì Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ti tọ́ka sí bí ìjọba mẹ́rin ṣe dé ipò agbára láti inú ilẹ̀ ọba Alẹkisáńdà, ó wá sọ pé: “Ní apá ìgbẹ̀yìn ìjọba wọn, bí àwọn olùrélànàkọjá ti ń gbé ìgbésẹ̀ lọ dé ìparí, ọba kan yóò dìde, tí ó rorò ní ojú, tí ó sì lóye àwọn ọ̀rọ̀ onítumọ̀ púpọ̀. Agbára rẹ̀ yóò sì di ńlá, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa agbára ti òun fúnra rẹ̀. Yóò sì fa ìparun ní ọ̀nà àgbàyanu, dájúdájú yóò kẹ́sẹ járí, yóò sì gbéṣẹ́. Ní ti tòótọ́, òun yóò run àwọn alágbára ńlá, àti àwọn tí í ṣe ẹni mímọ́. Àti gẹ́gẹ́ bí ìjìnlẹ̀ òye rẹ̀, dájúdájú, yóò mú kí ẹ̀tàn kẹ́sẹ járí ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú. Yóò sì gbé àgbéré ńláǹlà ní ọkàn-àyà rẹ̀, àti lákòókò òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn, yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀. Yóò sì dìde sí Olórí àwọn ọmọ aládé, ṣùgbọ́n a óò ṣẹ́ ẹ láìsí ọwọ́.”—Dáníẹ́lì 8:23-25.

  • Ta ní lè Dìde sí Olórí Àwọn Ọmọ Aládé?
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • ÌWO KÉKERÉ NÁÀ DI ALÁGBÁRA ŃLÁ

      16. (a) Inú ìwo ìṣàpẹẹrẹ wo ni ìwo kékeré náà ti jáde wá? (b) Báwo ni Róòmù ṣe di agbára ayé kẹfà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ṣùgbọ́n èé ṣe tí òun kì í fi í ṣe ìwo ìṣàpẹẹrẹ kékeré náà?

      16 Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe fi hàn, ìwo kékeré náà jáde wá láti inú ọ̀kan lára ìwo ìṣàpẹẹrẹ mẹ́rin náà—èyí tí ó sún mọ́ ìpẹ̀kun ìwọ̀-oòrùn jù lọ. Èyíinì ni àkóso ìjọba Hélénì ti Ọ̀gágun Kasáńdà lórí Makedóníà àti Gíríìsì. Nígbà tí ó yá, ìjọba Ọ̀gágun Lisimákù ọba Tírésì àti Éṣíà Kékeré wá gbé ìjọba yìí mì. Ní ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, ilẹ̀ Róòmù ṣẹ́gun àwọn ẹ̀ka ìwọ̀-oòrùn àgbègbè ìṣàkóso àwọn Hélénì yìí. Ìgbà tí ó sì fi máa di ọdún 30 ṣááju Sànmánì Tiwa, Róòmù gba gbogbo ìjọba àwọn Hélénì, ó sì sọ ara rẹ̀ di agbára ayé kẹfà ti inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Àmọ́, Ilẹ̀ Ọba Róòmù kọ́ ni ìwo kékeré inú ìran Dáníẹ́lì, nítorí pé ilẹ̀ ọba yẹn kò wà títí di “àkókò òpin tí a yàn kalẹ̀.”—Dáníẹ́lì 8:19.

      17. (a) Kí ni ìbátan tí ó wà láàárín ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ilẹ̀ Ọba Róòmù? (b) Báwo ni Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ṣe tan mọ́ ìjọba Hélénì ti Makedóníà àti Gíríìsì?

      17 Nígbà náà, kí wá ni ìtàn fi hàn pé ó jẹ́ “ọba kan” yẹn “tí ó rorò ní ojú”? Ní ti gidi, ìhà àríwá ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti yọ jáde. Títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Tiwa, àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù wà ní ibi tí ó di ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì báyìí. Nígbà tí ó ṣe, ìfàsẹ́yìn bá Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ṣùgbọ́n ayé ọ̀làjú ti àwọn Gíríìkì àti Róòmù ṣì ń bá a lọ láti nípa lórí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn apá yòókù Yúróòpù tí ó ti fìgbà kan rí wà lábẹ́ ìṣàkóso Róòmù. Octavio Paz, ará Mexico kan tí ó jẹ́ akéwì àti òǹkọ̀wé tí ó ti gba Ẹ̀bùn Nobel, kọ̀wé pé: “Nígbà tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣubú, Ṣọ́ọ̀ṣì gbapò rẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Àwọn Baba Ṣọ́ọ̀ṣì, àti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ẹ̀yìn ìgbà náà, gbé ẹ̀kọ́ ọgbọ́n èrò orí àwọn Gíríìkì wọnú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni.” Bertrand Russell, tí ó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ọgbọ́n èrò orí àti onímọ̀ ìṣirò ní ọ̀rúndún ogún, ṣàkíyèsí pé: “Ọ̀làjú ìhà Ìwọ̀-Oòrùn, tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn Gíríìkì wá, ni a gbé karí àṣà ọgbọ́n èrò orí àti sáyẹ́ǹsì tí ó bẹ̀rẹ̀ ní Mílétù [ìlú Gíríìsì kan tí ó wà ní Éṣíà Kékeré] ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì ààbọ̀ sẹ́yìn.” Nípa báyìí, a lè sọ pé inú ìjọba Hélénì ti Makedóníà àti Gíríìsì ni àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ti Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ti wá.

      18. Kí ni ìwo kékeré tí ó di ‘ọba tí ó rorò ní ojú’ ní “àkókò òpin”? Ṣàlàyé.

      18 Nígbà tí ó fi máa di ọdún 1763, Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ti ṣẹ́gun Sípéènì àti Faransé tí wọ́n jẹ́ ilẹ̀ alágbára tí ń bá a figẹ̀ wọngẹ̀. Láti ìgbà náà lọ ni Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ti di aláṣẹ lórí àwọn òkun àti agbára ayé keje inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Kódà lẹ́yìn tí àwọn ilẹ̀ mẹ́tàlá ní Àríwá Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ya kúrò lára ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1776, tí wọ́n sì dá Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sílẹ̀, Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì gbòòrò débi tí ó fi kó ìdá mẹ́rin ilẹ̀ ayé àti ìdá mẹ́rin àwọn ènìyàn inú rẹ̀ sábẹ́. Agbára ayé keje yìí tún lágbára sí i nígbà tí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n fi pa pọ̀ di agbára ayé aláwẹ́ méjì ti Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Lóòótọ́, agbára ayé yìí di “ọba kan . . . tí ó rorò ní ojú” nínú ọ̀ràn ọrọ̀ ajé àti agbára ológun. Nígbà náà, ìwo kékeré náà tí ó di agbára ìṣèlú tí ó rorò ní “àkókò òpin” ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà.

      19. Kí ni “Ìṣelóge” tí a mẹ́nu kàn nínú ìran náà?

      19 Dáníẹ́lì rí i pé ìwo kékeré náà “ń tóbi sí i gidigidi . . . síhà Ìṣelóge.” (Dáníẹ́lì 8:9) Ilẹ̀ Ìlérí tí Jèhófà fi fún àwọn ènìyàn àyànfẹ́ rẹ̀ dára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi pè é ní “ìṣelóge ilẹ̀ gbogbo,” èyíinì ni gbogbo ilẹ̀ ayé. (Ìsíkíẹ́lì 20:6, 15) Lóòótọ́, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gba Jerúsálẹ́mù ní December 9, 1917, nígbà tí ó sì di ọdún 1920, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní àṣẹ láti máa bójú tó ilẹ̀ Palẹ́sìnì, èyí tí ó ń bá a lọ títí di May 14, 1948. Ṣùgbọ́n ìran náà jẹ́ alásọtẹ́lẹ̀, tí ọ̀pọ̀ nǹkan inú rẹ̀ sì jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ. Ohun tí “Ìṣelóge” tí a mẹ́nu kàn nínú ìran náà sì ṣàpẹẹrẹ kì í ṣe Jerúsálẹ́mù bí kò ṣe ipò kan tí àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run kà sí mímọ́ wà lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò agbára ayé keje. Ẹ jẹ́ kí a wo bí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣe gbìyànjú láti halẹ̀ mọ́ àwọn ẹni mímọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́