ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọba Méjèèjì tó Wọ Gídígbò ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Òpin Wọn
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • 3, 4. Àwọn wo ni “àwọn tí ń ṣe ohun burúkú sí májẹ̀mú náà,” àjọṣepọ̀ wo ni wọ́n sì ní pẹ̀lú ọba àríwá?

      3 Áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn tí ń ṣe ohun burúkú sí májẹ̀mú náà ni òun [ọba àríwá] yóò sì ṣamọ̀nà sí ìpẹ̀yìndà nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in.” Áńgẹ́lì náà fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ Ọlọ́run wọn, wọn yóò borí, wọn yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́. Àti ní ti àwọn tí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye nínú àwọn ènìyàn náà, wọn yóò la ọ̀pọ̀ lóye. Dájúdájú, a óò mú wọn kọsẹ̀ nípa idà àti ọwọ́ iná, nípa oko òǹdè àti ìpiyẹ́, fún ọjọ́ mélòó kan.”—Dáníẹ́lì 11:32, 33.

  • Ọba Méjèèjì tó Wọ Gídígbò ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Òpin Wọn
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • 5, 6. Àwọn wo ni “àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ Ọlọ́run wọn,” kí ni nǹkan sì ti rí fún wọn lábẹ́ ọba àríwá?

      5 Àwọn Kristẹni tòótọ́ ńkọ́, ìyẹn, “àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ Ọlọ́run wọn,” àti “àwọn tí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye”? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tí ń gbé lábẹ́ àkóso ọba àríwá “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga,” wọn kì í ṣe apá kan ayé yìí. (Róòmù 13:1; Jòhánù 18:36) Bí wọ́n ṣe ń rí i dájú pé àwọn ń san “àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì,” lẹ́sẹ̀ kan náà wọ́n ń fi “àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 22:21) Tìtorí èyí, a pe ìwà títọ́ wọn níjà.—2 Tímótì 3:12.

      6 Nítorí èyí, àwọn Kristẹni tòótọ́ “kọsẹ̀” wọ́n sì tún “borí” bákan náà. Wọ́n kọsẹ̀ ní ti pé a ṣe inúnibíni lílekoko sí wọn, tí a tilẹ̀ pa àwọn mìíràn. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣẹ́gun ní ti pé ọ̀pọ̀ yanturu wọn dúró gbọn-in gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Wọ́n ṣẹ́gun ayé gan-an bí Jésù ti ṣe. (Jòhánù 16:33) Ní àfikún sí i, wọn kò dáwọ́ wíwàásù dúró rárá, kódà bí a bá tilẹ̀ jù wọ́n sẹ́wọ̀n tàbí sí ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Nípa ṣíṣe èyí, wọ́n “la ọ̀pọ̀ lóye.” Láìka inúnibíni ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ilẹ̀ tí ọba àríwá ń ṣàkóso sí, iye Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pọ̀ sí i. Nítorí ìṣòtítọ́ “àwọn tí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye,” “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí wọ́n túbọ̀ ń pọ̀ sí i níye, ti jáde wá ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyẹn.—Ìṣípayá 7:9-14.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́