-
Jèhófà Ṣí Ète Rẹ̀ PayáÌjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
-
-
12. Kí ni Jèhófà sọ pé kí Dáníẹ́lì ṣe? Kí nìdí?
12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà tipasẹ̀ Dáníẹ́lì àtàwọn wòlíì míì kọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó jẹ́ irú ọmọ tó ṣèlérí náà nígbà yẹn, kò tíì tó àsìkò lójú Jèhófà pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa ohun tó mí sí wọn pé kí wọ́n kọ sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Ọlọ́run mú kí Dáníẹ́lì rí ìran nípa bí a ṣe gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀, Jèhófà sọ fún un pé kó fi èdìdì di ìran náà títí dìgbà tí àsìkò á fi tó lójú òun. Tó bá wá dìgbà yẹn, ìmọ̀ tòótọ́ yóò “di púpọ̀ yanturu.”—Dán. 12:4.
Jèhófà tipasẹ̀ àwọn olóòótọ́ èèyàn bíi Dáníẹ́lì kọ ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa Ìjọba Mèsáyà
-
-
Jèhófà Ṣí Ète Rẹ̀ PayáÌjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
-
-
Ìmọ̀ Tòótọ́ Di Púpọ̀ Yanturu ní “Àkókò Òpin”
17. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè lóye òtítọ́ nípa Ìjọba náà? Ṣùgbọ́n kí la tún nílò?
17 Jèhófà sọ fún Dáníẹ́lì pé tó bá di “àkókò òpin,” ọ̀pọ̀ yóò “máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́” nípa ète Ọlọ́run yóò sì di púpọ̀ yanturu. (Dán. 12:4) Àwọn tó bá fẹ́ ní ìmọ̀ yẹn gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ní in. Ìwé ìwádìí kan sọ pé ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù tá a pè ní “lọ káàkiri” níbí túmọ̀ sí ni pé kéèyàn fara balẹ̀ ṣe àyẹ̀wò ìwé kan fínnífínní. Ṣùgbọ́n bó ṣe wù ká ṣàyẹ̀wò Bíbélì fínnífínní tó, òtítọ́ nípa Ìjọba náà kò lè yé wa dáadáa àfi tí Jèhófà bá mú kó yé wa.—Ka Mátíù 13:11.
18. Báwo làwọn tó bẹ̀rù Jèhófà ṣe fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀?
18 Bí Jèhófà ṣe ń ṣí ète rẹ̀ nípa Ìjọba náà payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nígbà díẹ̀ ṣáájú ọdún 1914 náà ló ṣe ń ṣí i payá nìṣó ní àkókò òpin yìí. A máa rí i ní Orí 4àti 5 ìwé yìí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ní láti ṣàtúnṣe sí òye wọn nípa àwọn ẹ̀kọ́ kan. Ṣùgbọ́n ṣé bí wọ́n ṣe ń ṣàtúnṣe òye wọn yìí wá fi hàn pé Jèhófà kò sí lẹ́yìn wọn ni? Rárá o! Ó wà lẹ́yìn wọn digbí. Kí nìdí tó fi wà lẹ́yìn wọn? Torí pé àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà yìí ní ànímọ́ méjì kan tó fẹ́ràn ni, ìyẹn ìgbàgbọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀. (Héb. 11:6; Ják. 4:6) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní ìgbàgbọ́ pé gbogbo ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Ìwé Mímọ́ yóò ṣẹ pátá. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ní ló sì ń jẹ́ kí wọ́n gbà pé àwọn ti ṣi bí àwọn ìlérí náà ṣe máa ṣẹ ní pàtó lóye. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wọn yìí hàn nínú ohun tí wọ́n sọ nínú Ilé Ìṣọ́ March 1, 1925, lédè Gẹ̀ẹ́sì. Wọ́n ní: “A mọ̀ pé Olúwa ló ń fúnra rẹ̀ túmọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti pé yóò túmọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà tó dára lójú rẹ̀, yóò sì jẹ́ nígbà tó bá tásìkò lójú rẹ̀.”
“Olúwa . . . yóò túmọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà tó dára lójú rẹ̀, yóò sì jẹ́ nígbà tó bá tásìkò lójú rẹ̀”
19. Òye wo ni Jèhófà ti wá jẹ́ ká ní báyìí, kí sì nìdí?
19 Nígbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́dún 1914, ìwọ̀nba òye ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ní nípa bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ Ìjọba náà yóò ṣe ṣẹ. (1 Kọ́r. 13:9, 10, 12) Torí pé a ń hára gàgà láti rí i pé àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣẹ, àwọn ìgbà kan wà tó jẹ́ pé ibi tí a fojú sí ọ̀nà kò gbabẹ̀. Ìrírí wa láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ti fi hàn pé ọ̀rọ̀ kan tí Ilé Ìṣọ́ tá a tọ́ka sí níṣàájú tún sọ bọ́gbọ́n mu gan-an ni. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ó jọ pé ohun tó yẹ ká máa fi sọ́kàn ni pé a kò lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ títí dìgbà tó bá ní ìmúṣẹ tàbí ìgbà tó bá ń ṣẹ lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n ní báyìí tí àkókò òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló ti ṣẹ, ọ̀pọ̀ sì ń ṣẹ lọ́wọ́. Torí pé àwa èèyàn Ọlọ́run jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a sì máa ń gba ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà bá fún wa, ó ti jẹ́ ká túbọ̀ ní òye kíkún nípa ète rẹ̀. Ìmọ̀ tòótọ́ sì ti wá pọ̀ yanturu lóòótọ́!
-