ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Dídá Àwọn Olùjọsìn Tòótọ́ mọ̀ ní Àkókò Òpin
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • 21. (a) Àkókò tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 12:11 yóò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí a bá mú kí ipò àwọn nǹkan wo wáyé? (b) Kí ni “apá pàtàkì ìgbà gbogbo,” ìgbà wo ni a sì mú un kúrò? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 298.)

      21 A sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Láti ìgbà tí a ti mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò, tí a sì ti gbé ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro kalẹ̀, yóò jẹ́ àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́.” Nípa báyìí, ìgbà tí a bá mú kí ipò àwọn nǹkan pàtó kan wáyé ni sáà yìí yóò tó bẹ̀rẹ̀. A óò ní láti mú “apá pàtàkì ìgbà gbogbo”—tàbí “ẹbọ tí ń bá a lọ láìdáwọ́dúró”a—kúrò. (Dáníẹ́lì 12:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Ẹbọ wo ni áńgẹ́lì yìí ní lọ́kàn? Kì í ṣe àwọn ẹbọ tí a máa ń fi ẹran rú nínú tẹ́ńpìlì èyíkéyìí lórí ilẹ̀ ayé. Kódà, tẹ́ńpìlì tí ó tilẹ̀ fìgbà kan wà ní Jerúsálẹ́mù rí pàápàá, kàn “jẹ́ ẹ̀dà ti òtítọ́” ni, ẹ̀dà tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jèhófà, tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹrẹu nígbà tí Kristi di Àlùfáà Àgbà tẹ́ńpìlì náà lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa! Nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí, tí ó dúró fún ìṣètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìjọsìn mímọ́ gaara, kò sídìí fún rírú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ títí lọ láìdáwọ́dúró, nítorí pé a ti “fi Kristi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀.” (Hébérù 9:24-28) Síbẹ̀síbẹ̀, gbogbo Kristẹni tòótọ́ ní ń rúbọ nínú tẹ́ńpìlì yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ [Kristi], ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) Nípa báyìí, ipò àkọ́kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí—mímú “apá pàtàkì ìgbà gbogbo” kúrò—wáyé ní ìdajì ọdún 1918, nígbà tí a fẹ́rẹ̀ẹ́ pa iṣẹ́ wíwàásù tì.

      22. (a) Kí ni “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro,” ìgbà wo ni a sì fi í lọ́lẹ̀? (b) Ìgbà wo ni àkókò tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 12:11 bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ni ó sì parí?

      22 Àmọ́, ipò kejì—ìfilọ́lẹ̀ tàbí ‘gbígbé ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro kalẹ̀’—wá ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú ìjíròrò wa nínú Dáníẹ́lì 11:31, ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro yẹn jẹ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lákọ̀ọ́kọ́, ó sì wá jáde wá gẹ́gẹ́ bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lẹ́yìn náà. Àwọn méjèèjì jẹ́ ohun ìríra ní ti pé a polongo wọn pé àwọn nìkan ṣoṣo ni aráyé gbójú lé pé wọ́n lè mú àlàáfíà wá. Nípa báyìí, nínú ọkàn-àyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àyè Ìjọba Ọlọ́run ni àwọn àjọ wọ̀nyí gbà ní ti gidi! January 1919 ni a gbé àbá Ìmùlẹ̀ yìí jáde fáráyé. Nígbà náà, ní àkókò yẹn, a mú ipò méjèèjì tí a tọ́ka sí nínú Dáníẹ́lì 12:11 ṣẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà [1,290] ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919, ó sì ń bá a lọ títí di ìgbà ìwọ́wé (ní Àríwá Ìlàjì Ayé) lọ́dún 1922.

      23. Báwo ni àwọn ẹni mímọ́ Ọlọ́run ṣe tẹ̀ síwájú dórí wíwà ní ipò àwọn tí a wẹ̀ mọ́ láàárín àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì orí kejìlá?

      23 Ní ìgbà yẹn, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́ tẹ̀ síwájú láti lè di àwọn tí a sọ di funfun tí a sì wẹ̀ mọ́ lójú Ọlọ́run bí? Dájúdájú wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀! A dá ààrẹ Watch Tower Society àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní March 1919. Lẹ́yìn náà ni a wá sọ pé wọn kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn èké tí a fi kàn wọ́n. Bí wọ́n ṣe mọ̀ pé iṣẹ́ púpọ̀ ṣì ń bẹ fún wọn láti ṣe, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sì ṣètò fún àpéjọpọ̀ kan ní September ọdún 1919. Ọdún yẹn kan náà ni a tẹ ẹ̀dà àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn tí ó ṣèkejì Ilé Ìṣọ́ jáde. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pàá, a pè é ní The Golden Age (Jí! nísinsìnyí), ó ti jẹ́ alátìlẹyìn gbágbáágbá fún Ilé Ìṣọ́ nínú fífi àìṣojo táṣìírí ìwà ìbàjẹ́ ayé yìí àti nínú ríran àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ láti máa wà ní mímọ́ nìṣó. Nígbà tí ó fi máa di òpin àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà, àwọn ènìyàn mímọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di àwọn tí a wẹ̀ mọ́, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí ipò mímọ́ padà. Ní September 1922, ní nǹkan bí ìgbà tí sáà yìí fẹ́ parí gẹ́lẹ́, wọ́n ṣe àpéjọpọ̀ pàtàkì kan ní ìlú Cedar Point, Ohio, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó fún ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù ní àlékún ìṣírí tó bùáyà. Ṣùgbọ́n, ó ṣì ń béèrè pé kí ìtẹ̀síwájú púpọ̀ sí i wà. Ìyẹn máa di ṣíṣe ní sáà àkànṣe tí yóò tẹ̀ lé e.

    • [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 298]

      ÌMÚKÚRÒ APÁ PÀTÀKÌ ÌGBÀ GBOGBO

      Nínú ìwé Dáníẹ́lì, ẹ̀ẹ̀marùn-ún ni gbólóhùn náà, “apá pàtàkì ìgbà gbogbo,” fara hàn. Ó tọ́ka sí ẹbọ ìyìn—“èso ètè”—tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run máa ń rú sí i déédéé. (Hébérù 13:15) Àsọtẹ́lẹ̀ pé a óò mú un kúrò ni a tọ́ka sí nínú Dáníẹ́lì 8:11; 11:31, àti 12:11.

      Nígbà ogun àgbáyé méjèèjì, a ṣe inúnibíni líle koko sí àwọn ènìyàn Jèhófà nínú ilẹ̀ “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù.” (Dáníẹ́lì 11:14, 15) Ìmúkúrò “apá pàtàkì ìgbà gbogbo” wáyé ní apá ìparí Ogun Àgbáyé Kìíní nígbà tí a fẹ́rẹ̀ẹ́ dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró ní àárín ọdún 1918. (Dáníẹ́lì 12:7) Bákan náà, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà mú “apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò” fún ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́. (Dáníẹ́lì 8:11-14; wo Orí Kẹwàá ìwé yìí.) “Àwọn apá” ìjọba Násì náà tún mú un kúrò fún àkókò tí Ìwé Mímọ́ kò sọ bí yóò ṣe gùn tó.—Dáníẹ́lì 11:31; wo Orí Kẹẹ̀ẹ́dógún ìwé yìí.

  • Dídá Àwọn Olùjọsìn Tòótọ́ mọ̀ ní Àkókò Òpin
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • Àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà January 1919 sí

      [1,290] ọjọ́: September 1922

      Dáníẹ́lì 12:11 (Àwọn Kristẹni Ẹni Àmì Òróró jí,

      wọ́n sì tẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí.)

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́