ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Dàn Wọn Wò—Ṣùgbọ́n Wọ́n Jẹ́ Olóòótọ́ Sí Jèhófà!
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • ÀWỌN TÍ Ó ṢE ṢÁMÚṢÁMÚ LÁRA ÀWỌN ÈWE JERÚSÁLẸ́MÙ

      7, 8. Kí ni a lè rí fàyọ láti inú Dáníẹ́lì 1:3, 4, àti 6, nípa ipò àtilẹ̀wá Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?

      7 Kì í ṣe àwọn nǹkan èlò inú tẹ́ńpìlì Jèhófà nìkan ni a kó wá sí Bábílónì. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Lẹ́yìn náà ni ọba sọ fún Áṣípénásì olórí òṣìṣẹ́ rẹ̀ láàfin pé kí ó mú àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ ọba àti ti àwọn ọ̀tọ̀kùlú wá, àwọn ọmọ tí kò ní àbùkù rárá, ṣùgbọ́n tí wọ́n dára ní ìrísí, tí wọ́n sì ní ìjìnlẹ̀ òye nínú ọgbọ́n gbogbo, tí wọ́n ní ìmọ̀ gan-an, tí wọ́n sì ní ìfòyemọ̀ ohun tí a mọ̀, tí wọ́n sì tún ní agbára láti dúró ní ààfin ọba.”—Dáníẹ́lì 1:3, 4.

      8 Àwọn wo ni a yàn? A sọ fún wa pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ Júdà wà lára wọn, Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà.” (Dáníẹ́lì 1:6) Èyí ni ó jẹ́ kí a ní òye díẹ̀ nípa ipò àtilẹ̀wá ti Dáníẹ́lì àti ti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tí ó fara sin. Bí àpẹẹrẹ, a ṣàkíyèsí pé wọ́n jẹ́ “àwọn ọmọ Júdà,” láti ìdílé ọba. Yálà wọ́n ti ìlà tí ń jọba wá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó bọ́gbọ́n mu láti ronú pé, ó kéré tán inú ìdílé sàràkí-sàràkí tí ó lẹ́nu ọ̀rọ̀ ni wọ́n ti wá. Yàtọ̀ sí pé èrò-inú wọn yè kooro tí ara wọn sì dá ṣáṣá, wọ́n tún ní ìjìnlẹ̀ òye, ọgbọ́n, ìmọ̀, àti ìfòyemọ̀—gbogbo èyí sì jẹ́ nígbà tí wọ́n ṣì kéré lọ́jọ́ orí tí a fi lè pè wọ́n ní “ọmọ,” bóyá ńṣe ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀dọ́langba. Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ti ní láti tayọ—àwọn tí ó ṣe ṣámúṣámú—láàárín àwọn èwe Jerúsálẹ́mù.

  • A Dàn Wọn Wò—Ṣùgbọ́n Wọ́n Jẹ́ Olóòótọ́ Sí Jèhófà!
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • ÌJÀKADÌ LÁTI YÍ ỌKÀN WỌN PADÀ

      10. Kí ni a fi kọ́ àwọn ọ̀dọ́ Hébérù wọ̀nyẹn, kí sì ni ète èyí?

      10 Lójú ẹ̀sẹ̀, ìjàkadì ti yíyí ọkàn ọmọdé ti àwọn ìgbèkùn wọ̀nyí padà bẹ̀rẹ̀. Láti rí i dájú pé a sọ àwọn ọ̀dọ́langba tí ó jẹ́ Hébérù wọ̀nyí di ẹni tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà ìgbàṣe-nǹkan ti àwọn ará Bábílónì, Nebukadinésárì pàṣẹ pé kí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ “kọ́ wọn ní ìkọ̀wé àti ahọ́n àwọn ará Kálídíà.” (Dáníẹ́lì 1:4) Èyí kì í ṣe ẹ̀kọ́ ṣákálá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia ṣàlàyé pé ó “ní nínú, kíkọ́ èdè Sumer, Ákádíánì, Árámáíkì . . . , àti àwọn èdè yòókù, àti àwọn ìwé rẹpẹtẹ tí a kọ ní èdè wọ̀nyẹn pẹ̀lú.” Ìwé ìtàn, ìṣirò, ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sánmà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni àpapọ̀ “àwọn ìwé rẹpẹtẹ tí a kọ ní èdè wọ̀nyẹn.” Ṣùgbọ́n, “àyọkà ọ̀rọ̀ ìsìn tí ń bá a rìn, tí ó jẹ́ ti àwọn àpẹẹrẹ abàmì àti ti ìwòràwọ̀-sọtẹ́lẹ̀ . . . , ni ó kó ipa pàtàkì níbẹ̀.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́