ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Gbogbo Ohun Tó Wà Níbi tí Omi Náà Ṣàn Dé Yóò Máa Wà Láàyè’
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • 3. Kí nìdí tí àwọn Júù àtijọ́ ò fi ka odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran sí odò gidi?

      3 Àwọn Júù àtijọ́ ò wo ìran nípa odò náà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí apá ibi tí wọ́n kà nínú Ìwé Mímọ́ yìí rán wọn létí àsọtẹ́lẹ̀ míì tí Ọlọ́run sọ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, èyí tó ṣeé ṣe kí wòlíì Jóẹ́lì ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn. (Ka Jóẹ́lì 3:18.) Nígbà táwọn Júù tó wà nígbèkùn ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí tí Jóẹ́lì kọ yẹn, wọn ò retí pé kí ‘wáìnì dídùn máa sẹ̀ láti orí àwọn òkè’ ní tààràtà; tàbí pé kí ‘wàrà máa ṣàn lórí àwọn òkè kéékèèké,’ bẹ́ẹ̀ ni wọn ò retí pé kí odò máa ṣàn jáde “láti ilé Jèhófà.” Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn Júù tó wà nígbèkùn gbà pé kì í ṣe odò gangan ni ohun tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ń tọ́ka sí.a Ó dáa, kí wá ni Jèhófà ń fi èyí sọ fún wọn? Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn apá kan nínú ìran yìí. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun mẹ́ta pàtàkì kan tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí mú kó dá wa lójú.

  • Àwọn Odò Ìbùkún Látọ̀dọ̀ Jèhófà
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • JÓẸ́LÌ 3:18 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ nípa omi tó ń sun láti ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì. Ó ṣàn jáde, ó sì lọ bomi rin ilẹ̀ gbígbẹ tó wà ní “Àfonífojì Àwọn Igi Bọn-ọ̀n-ní.” Torí náà, Jóẹ́lì àti Ìsíkíẹ́lì rí odò tó sọ aṣálẹ̀ di ibi tí nǹkan ti gbèrú. Ilé Jèhófà tàbí tẹ́ńpìlì ni omi méjèèjì ti ṣàn jáde.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́