ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ̀
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 18, 19. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jónà nínú ibú òkun lọ́hùn-ún? Irú ẹ̀dá inú omi wo ló gbé e mì, ta ló sì jẹ́ kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      18 Àmọ́ o, nǹkan kan ń da omi rú bọ̀! Nǹkan dúdú ni, ó tóbi fàkìàfakia, nǹkan abẹ̀mí sì ni. Ó sún mọ́ ọ̀dọ̀ Jónà, ó sì pa kuuru mọ́ ọn. Ó wá lanu wàà, ó sì gbé e mì.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 115]

      Jèhófà “ṣètò ẹja ńlá kan láti gbé Jónà mì”

      19 Jónà yóò ti rò pé ikú dé nìyẹn! Àmọ́, ó rí i pé ohun àrà kan ṣẹlẹ̀. Òun ṣì ń mí! Ẹja tó gbé e mì kò pa á lára, kò jẹ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ooru inú ẹja náà ò sì pa á. Àní Jónà ṣì wà láàyè, bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ibi tá a lè pè ní sàréè rẹ̀ ló wà! Ẹnu bẹ̀rẹ̀ sí í yà á gidigidi. Ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run Jónà ló “ṣètò ẹja ńlá kan láti gbé Jónà mì.”c—Jónà 1:17.

      20. Kí la lè rí kọ́ nípa Jónà látinú àdúrà tó gbà nínú ikùn ẹja ńlá náà?

      20 Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìṣẹ́jú ń gorí ìṣẹ́jú, wákàtí sì ń gorí wákàtí. Nínú òkùnkùn biribiri tí Jónà wà, ó ronú, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run. Orí kejì ìwé Jónà ni àdúrà tó gbà yìí wà, ó sì jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ nípa Jónà. Àdúrà yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jónà mọ Ìwé Mímọ́ gan-an, torí pé léraléra ló ń lo ọ̀rọ̀ inú ìwé Sáàmù. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní ẹ̀mí ìmoore, ìwà tó sì dáa ni. Jónà wá sọ níparí àdúrà rẹ̀ pé: “Ní tèmi, èmi yóò fi ohùn ìdúpẹ́ rúbọ sí ọ. Èmi yóò san ohun ti mo jẹ́jẹ̀ẹ́. Ti Jèhófà ni ìgbàlà.”—Jónà 2:9.

      21. Ẹ̀kọ́ wo ni Jónà kọ́ nípa ìgbàlà? Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ló yẹ ká máa rántí?

      21 Inú ibi téèyàn ò tiẹ̀ lè ronú kàn rárá yìí, ìyẹn ní “ìhà inú ẹja,” ni Jónà ti wá rí i pé Jèhófà lè gba ẹnikẹ́ni là níbikíbi àti nígbàkigbà. Àní sẹ́, Jèhófà rí ìránṣẹ́ rẹ̀ tó níṣòro yìí nínú ẹja tó wà lọ́hùn-ún, ó sì gbà á là. (Jónà 1:17) Jèhófà nìkan ló lè dá ẹ̀mí ẹnì kan sí nínú ẹja ńlá fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta kí nǹkan kan má sì ṣe onítọ̀hún. Lóde òní, ó yẹ kí àwa náà máa rántí pé Jèhófà ni “Ọlọ́run, ẹni tí èémí [wa] wà lọ́wọ́ rẹ̀.” (Dán. 5:23) Òun ni ẹlẹ́mìí tó ni ẹ̀mí wa, àti èémí tá à ń mí sínú. Ǹjẹ́ a moore Ọlọ́run? Ṣé kò wá yẹ ká máa pa àṣẹ Jèhófà mọ́?

      22, 23. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kó hàn bóyá Jónà ní ẹ̀mí ìmoore lóòótọ́? (b) Kí la rí kọ́ lára Jónà tó máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ṣe àṣìṣe?

      22 Jónà wá ńkọ́? Ṣé ó pa àṣẹ Jèhófà mọ́ láti fi hàn pé òun moore? Bẹ́ẹ̀ ni o. Lẹ́yìn ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, ẹja náà gbé Jónà wá sí etíkun, ó sì “pọ Jónà sórí ilẹ̀ gbígbẹ.” (Jónà 2:10) Àbẹ́ ò rí nǹkan, kò sí pé Jónà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sí etíkun! Àmọ́ ṣá, òun ló bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́nà ara rẹ̀ lọ láti etíkun ibi tí ẹja yẹn pọ̀ ọ́ sí. Kò pẹ́ kò jìnnà, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kó hàn bóyá Jónà ní ẹ̀mí ìmoore lóòótọ́. Ìwé Jónà 3:1, 2 sọ pé: “Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jónà wá nígbà kejì, pé: ‘Dìde, lọ sí Nínéfè ìlú ńlá títóbi náà, kí o sì pòkìkí fún un nípa ìpòkìkí tí èmi yóò sọ fún ọ.’” Kí ni Jónà wá ṣe?

  • Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ̀
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • c Nígbà tí àwọn atúmọ̀ èdè máa tú ọ̀rọ̀ tí àwọn Hébérù pe ẹja níbí sí èdè Gíríìkì, wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí “ẹran abàmì inú òkun” tàbí “ẹja tó tóbi fàkìà-fakia.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí bá a ṣe lè mọ irú ẹ̀dá inú omi tó gbé Jónà mì gan-an, ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ẹja àbùùbùtán kan wà nínú Òkun Mẹditaréníà tó tóbi débi pé wọ́n lè gbé odindi èèyàn mì. Àwọn ẹja àbùùbùtán tó tóbi jùyẹn lọ fíìfíì sì tún wà láwọn ibòmíì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹja àbùùbùtán kan wà tó gùn tó ọkọ̀ bọ́ọ̀sì mẹ́ta, ó sì ṣeé ṣe káwọn míì gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́