ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀
    Ilé Ìṣọ́—2009 | January 1
    • Àmọ́, dúró ná o! Nǹkan kan ń da omi rú, nǹkan ọ̀hún tóbi ó sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ Jónà, ó dúdú, nǹkan abẹ̀mí sì ni. Nǹkan ọ̀hún yọ sí i lójijì, ó sì pa kuuru mọ́ ọn. Ó lanu, ó sì gbé e mì.

      Bóyá ni Jónà ò ní parí ìgbésí ayé ẹ̀ síbí. Síbẹ̀, Jónà kíyè sí i pé ohun àrà kan ń ṣẹlẹ̀. Ó ṣì ń mí! Ẹja yẹn ò pa á lára, kò jẹ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ooru inú ẹja náà ò ṣeé ní nǹkan kan. Èèmọ̀ rèé o! Jónà ṣì wà láàyè, bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ibi tá a lè pè ní sàréè ló wà. Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ba Jónà. Kò sí àníàní pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ló “ṣètò ẹja ńlá kan láti gbé Jónà mì.”c—Jónà 1:17.

      Bí ìṣẹ́jú ti ń gorí ìṣẹ́jú, bẹ́ẹ̀ náà ni wákàtí ń gorí wákàtí. Nígbà tí Jónà wà níbi tó ṣókùnkùn jù lọ tó tíì rí rí yìí, ó ráyè ronú dáadáa, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run. Àdúrà tó gbà yẹn, tó wà ní orí kejì ìwé Jónà, sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa. Àdúrà yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jónà mọ Ìwé Mímọ́ gan-an, torí pé léraléra ló ń tọ́ka sáwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Sáàmù. Àdúrà yẹn tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jónà ní ànímọ́ kan tó máa ń múnú ẹni dùn, ìyẹn ẹ̀mí ìmoore. Nígbà tí Jónà máa parí àdúrà rẹ̀, ó sọ pé: “Ní tèmi, èmi yóò fi ohùn ìdúpẹ́ rúbọ sí ọ. Èmi yóò san ohun ti mo jẹ́jẹ̀ẹ́. Ti Jèhófà ni ìgbàlà.”—Jónà 2:9.

      Jónà wá kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà lè gba ẹnikẹ́ni là níbikíbi àti nígbàkigbà. Kódà ní “ìhà inú ẹja,” Jèhófà rí ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà nínú ìṣòro, ó sì gbà á là. (Jónà 1:17) Jèhófà nìkan ló lè pa ẹnì kan mọ́ láàyè láìséwu nínú ẹja ńlá kan fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta. Ó yẹ ká rántí lóde òní pé Jèhófà ni “Ọlọ́run, ẹni tí èémí [wa] wà lọ́wọ́ rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 5:23) Òun ló fun wa ní èémí tá à ń mí sínú, ìyẹn ìwàláàyè wa. Ṣá a moore Ọlọ́run? Ṣé kò wá yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Jèhófà?

      Jónà ńkọ́, ṣóhun náà fi hàn pé òun moore nípa ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni. Lẹ́yìn ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, ẹja náà gbé Jónà wá sí etíkun, ó sì “pọ Jónà sórí ilẹ̀ gbígbẹ.” (Jónà 2:10) Àbẹ́ ò rí nǹkan, kò sí pé Jónà ń lúwẹ̀ẹ́ dé etíkun! Àmọ́, fúnra ẹ̀ ló máa wá bó ṣe máa kúrò ní etíkun yẹn. Kò pẹ́ kò jìnnà, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ẹ̀mí ìmoore tí Jónà ní wá látọkàn ẹ̀. Ìwé Jónà 3:1, 2 sọ pé: “Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jónà wá nígbà kejì, pé: ‘Dìde, lọ sí Nínéfè ìlú ńlá títóbi náà, kí o sì pòkìkí fún un nípa ìpòkìkí tí èmi yóò sọ fún ọ.’” Kí ni Jónà máa ṣe?

  • Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀
    Ilé Ìṣọ́—2009 | January 1
    • c Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ táwọn Hébérù máa ń pe ẹja túmọ̀ sí “ẹran abàmì inú òkun” tàbí “ẹja tó tóbi fàkìà-fakia.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí bá a ṣe lè mọ irú ẹ̀dá inú omi tó jẹ́ gan-an, ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ẹja àbùùbùtán tó wà nínu Òkun Mẹditaréníà tóbi débi pé wọ́n lè gbé odindi èèyàn mì. Àwọn ẹja àbùùbùtán tó tóbi jùyẹn lọ fíìfíì sì tún wà láwọn ibòmíì, bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹja àbùùbùtán kan wà tó gùn tó ọkọ̀ bọ́ọ̀sì mẹ́ta, ó sì ṣeé ṣe káwọn míì gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ.

  • Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀
    Ilé Ìṣọ́—2009 | January 1
    • Kódà, àwọn nǹkan àgbàyanu máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì láìjẹ́ pé Ọlọ́run lọ́wọ́ sí i. Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́ pé lọ́dún 1758, atukọ̀ kan ré bọ́ sínú Òkun Mẹditaréníà látinú ọkọ̀ òkun rẹ̀, ẹja àbùùbùtán kan sì gbé e mì. Àmọ́, nígbà tí wọ́n yìnbọn lu ẹja náà, ó pọ atukọ̀ náà, wọ́n gbé e jáde kúrò nínú omi láàyè, ó sì fẹ́ẹ̀ máà sí nǹkan kan tó ṣe é. Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, a lè gbà pé nǹkan bàbàrà ni , kódà nǹkan àgbàyanu ni, àmọ́ kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu. Ṣé Ọlọ́run ò wá lè lo agbára rẹ̀ láti fi ṣe ohun tó jùyẹn lọ?

      Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ tún sọ pé kò sẹ́ni tó lè wà nínú ẹja fún ọjọ́ mẹ́ta tí ooru ò ní mú pa. Àmọ́, má gbàgbé pé àwọn èèyàn ti gbọ́n débi pé wọ́n lè tọ́jú atẹ́gùn tó pọ̀ gan-an pa mọ́ sínú àgbá kékeré kan kí wọ́n lè lò ó láti fi máa mí lábẹ́ omi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Ṣé Ọlọ́run ò wá ní lè lo agbára ńlá rẹ̀ tí ò láàlà àti ọgbọ́n rẹ̀ láti pa Jónà mọ́ láàyè kó sì máa mí fún ọjọ́ mẹ́ta? Bí áńgẹ́lì Jèhófà ṣe sọ fún Màríà, ìyá Jésù nígbà kan lọ̀rọ̀ rí, ó sọ pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.”—Lúùkù 1:37.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́