ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Kọ́ Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Aláàánú
    Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
    • Ọba pàápàá fi tọkàntọkàn bẹ̀rù Ọlọ́run. Ó dìde látorí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ aṣọ aláràbarà tó wọ̀, ó sì wọ irú aṣọ àpò ìdọ̀họ táwọn aráàlú wọ̀, kódà ó “jókòó nínú eérú.” Òun àtàwọn “ẹni ńlá” rẹ̀ ìyẹn àwọn ìjòyè rẹ̀, sì pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn ará ìlú Nínéfè gbààwẹ̀, bí wọ́n ṣe sọ ààwẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ yẹn di àṣẹ fún gbogbo aráàlú nìyẹn. Ọba pàṣẹ pé kí gbogbo aráàlú, títí kan àwọn ẹran agbéléjẹ̀, wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ.c Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ló fi gbà pé àwọn èèyàn òun jẹ̀bi ìwàkiwà àti pé ìwà ipá kún ọwọ́ wọn. Ó sì nírètí pé Ọlọ́run tòótọ́ máa ṣàánú àwọn nígbà tó bá rí báwọn ṣe ronú pìwà dà, ó ní: “Ọlọ́run . . . lè yí padà . . . kúrò nínú ìbínú rẹ̀ jíjófòfò, kí a má bàa ṣègbé.”—Jónà 3:6-9.

  • Ó Kọ́ Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Aláàánú
    Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
    • c Ó lè dà bíi pé ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣàjèjì, àmọ́ tiwọn kọ́ làkọ́kọ́ láyé ìgbà yẹn. Òpìtàn ará Gíríìkì kan tó ń jẹ́ Herodotus, sọ pé nígbà táwọn ará Páṣíà àtijọ́ ń ṣọ̀fọ̀ ikú olórí ológun kan tí wọ́n fẹ́ràn dáadáa, àwọn àtàwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn ni wọ́n jọ ṣọ̀fọ̀ yẹn níbàámu pẹ̀lú àṣà wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́