ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ̀
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • 12. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká kàn gbà pé ṣe ni Jónà ò bìkítà bó ṣe sùn nígbà tí ìjì ń jà? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tó fa ìyọnu tó bá wọn?

      12 Bó ṣe wá rí i pé kò sí nǹkan kan tóun lè ṣe sí ọ̀ràn náà, ó lọ wá ibì kan sùn sí nínú ọkọ̀ náà. Ó sì sùn lọ fọnfọn.b Ọ̀gá atukọ̀ náà rí i níbi tó sùn sí, ló bá jí i pé kí òun náà ké pe ọlọ́run rẹ̀. Bí àwọn atukọ̀ náà ṣe rí i pé ìjì tó ń jà kì í ṣe ojú lásán, wọ́n ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè mọ ẹni tó fa ìyọnu náà láàárín àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀. Ó dájú pé àyà Jónà á ti máa já bí kèké náà ṣe ń fò wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan. Nígbà tó yá, àṣírí tú. Àṣé torí Jónà ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí ìjì náà jà, òun náà sì ni Jèhófà jẹ́ kí kèké mú.—Ka Jónà 1:5-7.

  • Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ̀
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • b Bíbélì Septuagint sọ pé Jónà hanrun láti fi sọ bó ṣe sùn wọra tó. Àmọ́, ká má kàn gbà pé Jónà ò bìkítà nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ló ṣe lọ wábi sùn sí o. Ká rántí pé nígbà míì ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn máa ń jẹ́ kí oorun kunni. Nígbà tí Jésù wà nínú ìrora ní ọ̀gbà Gẹtisémánì, ńṣe ni Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù “ń tòògbé nítorí ẹ̀dùn-ọkàn.”—Lúùkù 22:45.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́