ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Jẹ́ Ká Wà Lára Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́
    Ilé Ìṣọ́—1999 | December 15
    • 8. Báwo ni àpẹẹrẹ Hábákúkù ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn Kristẹni tó wà ní ọ̀rúndún kìíní àti lóde òní?

      8 Hábákúkù ò mọ bí ìparun Jerúsálẹ́mù ti sún mọ́lé tó. Bákan náà ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ò mọ ìgbà tí ètò àwọn nǹkan ti àwọn Júù yóò dópin. Lónìí, àwa pẹ̀lú ò mọ “ọjọ́ àti wákàtí” tí ìdájọ́ Jèhófà yóò dé sórí ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (Mátíù 24:36) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká kíyè sí ìdáhùn alápá méjì tí Jèhófà fún Hábákúkù. Èkíní, ó mú un dá wòlíì náà lójú pé òpin yóò dé nígbà tí àkókò bá tó. Ọlọ́run wí pé: “Kì yóò pẹ́,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé lójú èèyàn, ó lè jọ pé ọ̀ràn náà ń falẹ̀. (Hábákúkù 2:3) Èkejì, Jèhófà rán Hábákúkù létí pé: “Ní ti olódodo, òun yóò máa wà láàyè nìṣó nípa ìṣòtítọ́ rẹ̀.” (Hábákúkù 2:4) Ẹ ò ri pé òdodo ọ̀rọ̀ pọ́ńbélé lèyí! Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ká máa gbé ìgbésí ayé tó fi ìgbàgbọ́ hàn, kì í ṣe ká máa ṣírò ìgbà tí òpin yóò dé.

      9. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà onígbọràn ṣe ń wà láàyè nìṣó nípasẹ̀ ìṣòtítọ́ wọn (a) lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa? (d) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká fún ìgbàgbọ́ wa lókun?

      9 Nígbà tí ogun kó Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jeremáyà, akọ̀wé rẹ̀ Bárúkù, Ebedi-mélékì, àti àwọn adúróṣinṣin ọmọ Rékábù rí i pé òótọ́ ní ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Hábákúkù. Wọ́n ń “wà láàyè nìṣó” ní ti pé, wọ́n yọ nínú ìparun burúkú tó dé bá Jerúsálẹ́mù. Èé ṣe? Jèhófà ló san èrè ìṣòtítọ́ wọn fún wọn. (Jeremáyà 35:1-19; 39:15-18; 43:4-7; 45:1-5) Bákan náà, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó jẹ́ Hébérù ò fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ṣeré rárá, nítorí pé nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù dó ti Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, tí wọ́n sì tún kógun wọn lọ láìsẹ́ni tó mọ ohun tí wọ́n rí, àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ṣì fi ẹ̀mí ìgbàgbọ́ ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Jésù pé kí wọ́n tètè yáa bẹ́sẹ̀ wọn sọ̀rọ̀. (Lúùkù 21:20, 21) Ìṣòtítọ́ wọn ló mú kí wọ́n máa wà láàyè nìṣó. Bákan náà, àwa náà yóò máa wà láàyè nìṣó bí òpin náà bá bá wa gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Ẹ ò ri pé ìdí pàtàkì lèyí jẹ́ táa fi ní láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun nísinsìnyí!

  • Ẹ Jẹ́ Ká Wà Lára Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́
    Ilé Ìṣọ́—1999 | December 15
    • a Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú ìtumọ̀ Septuagint ti Hábákúkù 2:4, èyí tó ní gbólóhùn náà nínú pé “bó bá fà sẹ́yìn, ọkàn mi kò ni inú dídùn sí i.” Gbólóhùn yìí kò fara hàn rárá nínú ìwé àfọwọ́kọ ti èdè Hébérù èyíkéyìí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí. Àwọn kan sọ pé àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti èdè Hébérù kan tí kò sí mọ́ ni wọ́n gbé ìtumọ̀ Septuagint yẹn kà. Bó ti wù kó rí, ẹ̀mí mímọ́ ló mí sí Pọ́ọ̀lù tó fi fi gbólóhùn yìí kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ níhìn-ín. Nítorí náà, Ọlọ́run ló fún un láṣẹ láti sọ bẹ́ẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́