-
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kó O Lè Wà Láàyè!Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018 | November
-
-
7. Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí Hábákúkù sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀?
7 Ka Hábákúkù 1:5-7. Lẹ́yìn tí Hábákúkù sọ gbogbo ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún Jèhófà, ó lè máa ronú nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe. Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó sì mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára Hábákúkù, torí náà kò bá a wí fún bó ṣe sọ tinú rẹ̀ jáde. Ọlọ́run mọ̀ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn ń kó ìbànújẹ́ bá a, torí náà ó sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù aláìṣòótọ́ fún Hábákúkù. Kódà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun lẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà sọ fún pé òun máa tó pa àwọn oníwàkiwà yẹn run.
8. Kí nìdí tí ohun tí Jèhófà sọ fi ya Hábákúkù lẹ́nu?
8 Jèhófà sọ fún Hábákúkù pé òun máa tó gbé ìgbésẹ̀. Ó fi dá Hábákúkù lójú pé òun máa lo àwọn ará Kálídíà láti fìyà jẹ àwọn èèyànkéèyàn yẹn, ìyẹn àwọn ará Júdà. Nígbà tí Jèhófà sọ pé “ní àwọn ọjọ́ yín,” ohun tó ń sọ ni pé òun máa mú ìdájọ́ wá sórí àwọn èèyàn yẹn nígbà ayé wòlíì Hábákúkù tàbí nígbà ayé àwọn tí wọ́n jọ gbáyé. Ohun tí Jèhófà sọ yìí fi hàn pé ìyà máa jẹ gbogbo àwọn ará Júdà.a Ohun tí Hábákúkù ń retí kí Jèhófà fi dá a lóhùn kọ́ nìyí. Àwọn ará Kálídíà (ìyẹn àwọn ará Bábílónì) burú gan-an kódà wọ́n rorò ju ataare. Tó bá kan ti ìwà ipá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kéré sí wọn torí àwọn mọ ìlànà Jèhófà. Kí ló wá dé tó fi jẹ́ pé orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó burú yìí ni Jèhófà fẹ́ lò láti fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀? Tó bá jẹ́ ìwọ ni Hábákúkù, báwo lohun tí Jèhófà sọ yìí ṣe máa rí lára rẹ?
-
-
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kó O Lè Wà Láàyè!Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018 | November
-
-
a Hábákúkù 1:5 lo ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ náà “yín” láti fi hàn pé kò sẹ́ni tí kò ní mọ̀ ọ́n lára nígbà tí wọ́n bá pa Júdà run.
-