ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ẹ Dúró Dè Mí”
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | March 1
    • 3 Ohun tí ó yẹ fún àfiyèsí ni òkodoro òtítọ́ náà pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sefaniah pòkìkí ìdájọ́ àtọ̀runwá lòdì sí “àwọn olórí” elétò ìlú Juda (àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí àwọn ìjòyè ẹ̀yà) àti “àwọn ọmọkùnrin ọba,” nínú lámèyítọ́ rẹ̀, kò fìgbà kankan mẹ́nu kan ọba náà fúnra rẹ̀.a (Sefaniah 1:8; 3:3, NW) Èyí fi hàn pé Ọba Josiah ọ̀dọ́ ti fi ìfẹ́ hàn tẹ́lẹ̀ fún ìjọsìn mímọ́ gaara, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, ní ojú ìwòye ipò tí Sefaniah lòdì sí, ó hàn gbangba pé kò tí ì bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe ìsìn. Gbogbo èyí fi hàn pé, Sefaniah sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní Juda ní kùtùkùtù àwọn ọdún Josiah, ẹni tí ó ṣàkóso láti ọdún 659 sí 629 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Láìṣiyèméjì, bí Sefaniah ṣe fi tagbáratagbára sọ àsọtẹ́lẹ̀ túbọ̀ mú kí Josiah ọ̀dọ́ wà lójúfò sí ìbọ̀rìṣà, ìwà ipá, àti ìwà ìbàjẹ́ tí ó gbalégbòde ní Juda ní àkókò náà, ó sì fún ìgbétásì rẹ̀ ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn lòdì sí ìbọ̀rìṣà níṣìírí.—2 Kronika 34:1-3.

  • “Ẹ Dúró Dè Mí”
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | March 1
    • a Yóò dà bíi pé gbólóhùn náà, “àwọn ọmọkùnrin ọba,” ń tọ́ka sí gbogbo àwọn ọmọ aládé, níwọ̀n bí àwọn ọmọ Josiah fúnra rẹ̀ ṣì kéré ní àkókò náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́