-
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Náhúmù, Hábákúkù àti SefanáyàIlé Ìṣọ́—2007 | November 15
-
-
3:9—Kí ni “èdè mímọ́ gaara,” báwo la sì ṣe ń sọ ọ́? Òótọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tá a rí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, títí kan gbogbo ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ àwọn èèyàn. À ń sọ ọ́ nípa gbígba òtítọ́ gbọ́, nípa fífi kọ́ àwọn èèyàn àti nípa mímú ìgbésí ayé wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.
-
-
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Náhúmù, Hábákúkù àti SefanáyàIlé Ìṣọ́—2007 | November 15
-
-
3:8, 9. Bá a ṣe ń dúró de Jèhófà, à ń retí ìgbàlà nípa kíkọ́ “èdè mímọ́ gaara” àti nípa pípè tá à ń ‘pe orúkọ Ọlọ́run,’ èyí tá a sì ń ṣe nípa yíyà tẹ́nì kọ̀ọ̀kan ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún un. A tún ń sin Jèhófà “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀, a sì ń “rú ẹbọ ìyìn” gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tá à ń mú wá fún Ọlọ́run.—Hébérù 13:15.
-