-
“Ẹni Rírẹlẹ̀ ní Ọkàn-Àyà Ni Èmi”“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
-
-
ORÍ KẸTA
“Ẹni Rírẹlẹ̀ ní Ọkàn-Àyà Ni Èmi”
“Wò ó! Ọba rẹ fúnra rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá”
1-3. Báwo ni Jésù ṣe wọ̀lú Jerúsálẹ́mù, kí sì nìdí tíyẹn fi lè ya àwọn kan nínú ogunlọ́gọ̀ àwọn aráàlú tó ń wò ó lẹ́nu?
ŃṢE ni gbogbo Jerúsálẹ́mù ń kùn yùnmùyùnmù. Èèyàn ńlá kan ló fẹ́ dé bá Jerúsálẹ́mù lálejò! Gbogbo aráàlú ti wà lẹ́bàá ọ̀nà lẹ́yìn òde ìlú Jerúsálẹ́mù. Torí ohun méjì kọ́, torí àtikí ọkùnrin yìí káàbọ̀ ni, àwọn kan tiẹ̀ ń sọ pé ajogún Ọba Dáfídì ni, pé òun lẹni tó tọ́ láti jẹ́ Alákòóso Ísírẹ́lì. Àwọn kan ń mi imọ̀ ọ̀pẹ gẹ́gẹ́ bí àmì ìkíni; àwọn míì tẹ́ aṣọ àtàwọn ewé igi sójú ọ̀nà kí ọ̀nà bàa lè tẹ́ dáadáa níwájú àlejò pàtàkì náà. (Mátíù 21:7, 8; Jòhánù 12:12, 13) Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ nínú wọn ti máa retí àrà tẹ́ni yìí máa dá nígbà tó bá ń wọ̀lú bọ̀.
2 Ó lè jẹ́ pé ohun táwọn kan ń retí ni pé kó wọ̀lú tìlù-tìfọn. Wọn ò ṣàìmọ àwọn lóókọlóókọ tó ti wọ̀lú tìlù-tìfọn bẹ́ẹ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, Ábúsálómù ọmọ Dáfídì pera ẹ̀ lọ́ba; àádọ́ta ọkùnrin ló ní kí wọ́n máa gẹṣin lọ níwájú òun. (2 Sámúẹ́lì 15:1, 10) Júlíọ́sì Késárì tó jẹ́ Olùṣàkóso Róòmù fẹlá jù bẹ́ẹ̀ lọ; ìgbà kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé torí pé ó jáwé olùborí, ńṣe ló kó èrò rẹpẹtẹ sẹ́yìn tí wọ́n sì jọ wọlé òrìṣà Júpítà tí wọ́n kọ́ sórí òkè, ìyẹn òkè tó kéré jù lára àwọn òkè méje tó wà nílùú Róòmù. Ogójì erin tò sápá ọ̀tún, ogójì tò sápá òsì, gbogbo wọn ló sì gbéná lérí. Àmọ́, ẹni táwọn aráàlú Jerúsálẹ́mù ń retí lọ́tẹ̀ yìí kì í ṣẹgbẹ́ àwọn tá a sọ yẹn lọ́nà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Yálà ó yé àwọn ogunlọ́gọ̀ náà o tàbí kò yé wọn o, Mèsáyà lèyí, ẹni bíi tiẹ̀ ò tíì sí láyé rí. Ìgbà tí Ọba lọ́la yìí sì fi máa wá wọ̀lú Jerúsálẹ́mù, ohun táwọn kan nínú wọn rí ní láti yà wọ́n lẹ́nu.
3 Wọn ò rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin, kò sí àwọn sárésáré, kò sí ẹṣin, ó sì dájú pé kò sí erin kankan. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lásánlàsàn, ẹran arẹrù tẹ́nikẹ́ni ò kà sí ni Jésù gùn wọ Jerúsálẹ́mù.a Ẹni tó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yìí ò wọṣọ gẹ̀gẹ̀-ruru kan sọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò dáṣọ sọ́rùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó gùn lárà ọ̀tọ̀. Èyí táwọn ọlọ́lá kan á fi fawọ olówó iyebíye di ẹṣin wọn ní gàárì, aṣọ táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó sún mọ́ ọn tẹ́ sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ni Jésù jókòó lé. Kí ni ì báà dé tí Jésù fi ní láti wọ̀lú Jerúsálẹ́mù láìpàfíyèsí bẹ́ẹ̀ nígbà táwọn tí ò tiẹ̀ lọ́lá tó o rárá àti rárá ń wọ̀lú tìlù-tìfọn?
4. Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí Mèsáyà Ọba ṣe máa wọ Jerúsálẹ́mù?
4 Àsọtẹ́lẹ̀ kan báyìí ni Jésù ń mú ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Kún fún ìdùnnú gidigidi . . . Kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù. Wò ó! Ọba rẹ fúnra rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá. Ó jẹ́ olódodo, bẹ́ẹ̀ ni, ẹni ìgbàlà; onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ẹran tí ó ti dàgbà tán, ọmọ abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” (Sekaráyà 9:9) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi hàn pé lọ́jọ́ kan, Ẹni tí Ọlọ́run dìídì yàn, ìyẹn Mèsáyà á fira rẹ̀ han àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù pé òun ni Ọba tí Ọlọ́run yàn. Síwájú sí í, bó ṣe máa wọ̀lú àti irú ẹran tó máa gùn wọ̀lú á jẹ́ káwọn èèyàn lè rí ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ rere tó ní. Ànímọ́ ọ̀hún sì ni ìrẹ̀lẹ̀.
-
-
“Ẹni Rírẹlẹ̀ ní Ọkàn-Àyà Ni Èmi”“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
-
-
a Nígbà tí ìwé kan ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó ní “ẹran tí kò jọjú” ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó fi kún un pé: “Wọn ò kì í ṣe ẹran tó já fáfá, wọ́n lórí kunkun, ẹran táwọn tálákà sábà máa ń fi ṣiṣẹ́ ni àti pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́wà.”
-