-
Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Yóò Ti Ṣàṣeyọrí!Ilé Ìṣọ́—2008 | July 15
-
-
Àpèjúwe Ìwúkàrà
9, 10. (a) Kí ni Jésù fi àpèjúwe ìwúkàrà ṣàlàyé? (b) Nínú Bíbélì, kí ni ìwúkàrà sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ, ìbéèrè wo la sì máa gbé yẹ̀ wò nípa àpèjúwe ìwúkàrà tí Jésù ṣe?
9 Kì í ṣe gbogbo ìgbà lèèyàn máa ń fojú rí ọ̀nà tí irúgbìn gbà ń dàgbà. Ohun tí Jésù ṣàlàyé nínú àpèjúwe tó sọ tẹ̀ lé e nìyẹn. Ó ní: “Ìjọba ọ̀run dà bí ìwúkàrà, èyí tí obìnrin kan mú, tí ó sì fi pa mọ́ sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ńlá mẹ́ta, títí gbogbo ìṣùpọ̀ náà fi di wíwú.” (Mát. 13:33) Kí ni ìwúkàrà yìí dúró fún, báwo ló sì ṣe kan ìtẹ̀síwájú Ìjọba Ọlọ́run?
10 Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń fi ìwúkàrà ṣàpẹẹrẹ ẹ̀ṣẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ìwúkàrà lọ́nà yìí, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó wà nínú ìjọ Kọ́ríńtì ìgbàanì ṣe lè ní ipa búburú lórí àwọn ará. (1 Kọ́r. 5:6-8) Ṣé Jésù wá ń lo ìwúkàrà láti fi ṣàpẹẹrẹ ìbísí ohun tí kò dára ni?
11. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń lo ìwúkàrà láyé ọjọ́un?
11 Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ó yẹ ká gbé àwọn kókó mẹ́ta pàtàkì kan yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyè láti lo ìwúkàrà nígbà àjọyọ̀ Ìrékọjá, nígbà míì ó máa ń tẹ́wọ́ gba ẹbọ tó ní ìwúkàrà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń lo ìwúkàrà nígbà ẹbọ ìdàpọ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ìdúpẹ́, èyí tó jẹ́ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe tí wọ́n fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ìbùkún rẹ̀. Àkókò oúnjẹ ayọ̀ lèyí sì máa ń jẹ́.—Léf. 7:11-15.
12. Kí la rí kọ́ látinú bí Bíbélì ṣe ń lo àfiwé?
12 Ìkejì, nínú Bíbélì wọ́n máa ń lo ohun kan láti fi ṣàkàwé nǹkan kan tí kò dára, nígbà míì wọ́n sì lè lo ohun kan náà láti ṣàkàwé ohun tó tọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ohun tó wà nínú 1 Pétérù 5:8 níbi tí wọ́n ti fi kìnnìún ṣàpẹẹrẹ bíi Sátánì ṣe jẹ́ ẹhànnà, àti eléwu ẹ̀dá. Àmọ́ Bíbélì tún fi Jésù wé kìnnìún nínú Ìṣípayá 5:5, ó pè é ní “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà.” Nínú ọ̀ràn ti Jésù, ńṣe ni Bíbélì fi kìnnìún ṣàpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo tí kì í bẹ̀rù ohunkóhun.
13. Kí ni àpèjúwe Jésù nípa ìwúkàrà jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tó ń mú kẹ́nì kan di ọmọlẹ́yìn Kristi?
13 Ìkẹta, nínú àpèjúwe ìwúkàrà yẹn, Jésù kò sọ pé ìwúkàrà náà sọ gbogbo ìyẹ̀fun di èyí tí kò wúlò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló kàn ń sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe búrẹ́dì. Ńṣe lobìnrin yẹn mọ̀ọ́mọ̀ fi ìwúkàrà sí ìyẹ̀fun náà, gbogbo ìyẹ̀fun náà sì wú bó ṣe ń fẹ́. Níwọ̀n bí obìnrin yìí ti fi ìwúkàrà náà pa mọ́ sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun náà, kò fojú rí bí ìyẹ̀fun náà ṣe ń wú. Èyí jẹ́ ká rántí àpèjúwe ọkùnrin tó fúnrúgbìn, tó sì lọ sùn lóru. Jésù sọ pé: “Irúgbìn náà sì rú jáde, ó sì dàgbà sókè, gan-an bí ó ṣe ṣẹlẹ̀, [ọkùnrin náà] kò mọ̀.” (Máàkù 4:27) Àpèjúwe yìí rọrùn gan-an láti fi ṣàlàyé bá ò ṣe lè mọ ohun tó ń mú kẹ́nì kan di ọmọlẹ́yìn Kristi. Ó ṣeé ṣe kí á má rí ìtẹ̀síwájú ẹni náà níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ ìtẹ̀síwájú yẹn máa ń hàn kedere nígbẹ̀yìn.
14. Apá wo nínú iṣẹ́ ìwàásù ni Jésù fi bí ìwúkàrà náà ṣe sọ gbogbo ìṣùpọ̀ di wíwú ṣàkàwé?
14 Kì í ṣe pé èèyàn ò fojú rí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń tẹ̀ síwájú nìkan ni, ó tún ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Èyí ni ohun mìíràn tí Jésù fi àpèjúwe ìwúkàrà ṣàlàyé. Ńṣe ni ìwúkàrà yìí sọ gbogbo ìṣùpọ̀ náà di wíwú, ìyẹn “òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ńlá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.” (Lúùkù 13:21) Bíi ti ìwúkàrà yẹn, iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tó ń jẹ́ kí iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn máa pọ̀ sí i ti gbòòrò débi pé, a ti wàásù Ìjọba Ọlọ́run dé “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8; Mát. 24:14) Àǹfààní ńlá mà ló jẹ́ fún wa o, pé a wà lára àwọn tó ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò sí i lọ́nà tó pẹtẹrí bẹ́ẹ̀!
-
-
Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Yóò Ti Ṣàṣeyọrí!Ilé Ìṣọ́—2008 | July 15
-
-
20, 21. (a) Kí la rí kọ́ látinú àyẹ̀wò àwọn àpèjúwe Jésù nípa bí irúgbìn ṣe ń dàgbà? (b) Kí ni ìpinnu rẹ báyìí?
20 Kí la ti wá rí kọ́ látinú àyẹ̀wò ráńpẹ́ tá a ṣe nípa àwọn àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa bí irúgbìn ṣe ń dàgbà? Àkọ́kọ́, bí irúgbìn hóró músítádì tí Jésù sọ ṣe dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tó ń kọbi ara sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé. Kò sóhun tó lè dá iṣẹ́ Jèhófà dúró kó má tàn kálẹ̀! (Aísá. 54:17) Láfikún sí i, Ọlọ́run tún ń dáàbò bo àwọn tó ń wá “ibùwọ̀ lábẹ́ òjìji [igi] náà” kúrò lọ́wọ́ Sátánì àti ayé burúkú rẹ̀. Ìkejì, Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà. Gẹ́lẹ́ bí ìwúkàrà tí obìnrin yẹn fi pa mọ́ sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ṣe sọ gbogbo rẹ̀ di wíwù láìjẹ́ pé obìnrin yẹn fojú rí i, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé, a kì í sábà fojú rí ìtẹ̀síwájú tó ń wáyé, àmọ́ ó ń ṣẹlẹ̀ dájúdájú! Ìkẹta, kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ìhìn rere ló ń di ọmọlẹ́yìn. Àwọn kan ti dà bí ẹja tí kò yẹ, tí Jésù sọ nínú àpèjúwe rẹ̀.
-