ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò Bí Oòrùn”
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 15
    • 2. Nínú àpèjúwe Jésù nípa àlìkámà àti àwọn èpò, kí ni irúgbìn àtàtà náà ṣàpẹẹrẹ?

      2 Àmọ́, ọ̀kan lára àwọn àpèjúwe Jésù dá lórí bó ṣe máa ṣe àkójọ àwọn tó máa bá a ṣèjọba. Èyí ni àkàwé àlìkámà àti àwọn èpò, èyí tó wà nínú Mátíù orí 13. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù sọ fún wa nínú àpèjúwe mìíràn pé irúgbìn náà ni “ọ̀rọ̀ ìjọba náà,” àmọ́ nínú àpèjúwe yìí, ó sọ fún wa pé irúgbìn àtàtà náà ṣàpẹẹrẹ ohun kan tó yàtọ̀, ìyẹn ni “àwọn ọmọ ìjọba náà.” (Mát. 13:38) Àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́, wọ́n jẹ́ “àwọn ọmọ,” tàbí àwọn ajogún, Ìjọba náà.—Róòmù 8:14-17; ka Gálátíà 4:6, 7.

  • “Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò Bí Oòrùn”
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 15
    • 4. (a) Ta ni ọkùnrin inú àpèjúwe náà? (b) Ìgbà wo ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí fún irúgbìn yìí, báwo ló sì ṣe ṣe é?

      4 Ta ni ọkùnrin tó fún irúgbìn àtàtà sínú pápá rẹ̀? Jésù sọ ẹni tí ọkùnrin náà jẹ́ nínú àlàyé tó ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn tó sọ àpèjúwe yìí, ó ní: “Afúnrúgbìn tí ó fún irúgbìn àtàtà náà ni Ọmọ ènìyàn.” (Mát. 13:37) Láàárín ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ tí Jésù, tó jẹ́ “Ọmọ ènìyàn” fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ló ṣètò pápá náà sílẹ̀ kó bàa lè ṣeé gbin irúgbìn sí. (Mát. 8:20; 25:31; 26:64) Lẹ́yìn náà, láti Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó bẹ̀rẹ̀ sí fún irúgbìn àtàtà, ìyẹn “àwọn ọmọ ìjọba náà.” Ó dájú pé fífún irúgbìn yìí wáyé nígbà tí Jésù, tó jẹ́ aṣojú Jèhófà, bẹ̀rẹ̀ sí tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀mí yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.b (Ìṣe 2:33) Irúgbìn àtàtà náà dàgbà ó sì di àlìkámà. Nítorí náà, ìdí tí Jésù fi fún irúgbìn àtàtà náà jẹ́ láti ṣe àkójọ gbogbo àwọn tó máa di ajùmọ̀jogún pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n sì máa bá a ṣèjọba.

  • “Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò Bí Oòrùn”
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 15
    • 5. Ta ni ọ̀tá inú àpèjúwe náà, àwọn wo sì làwọn èpò ṣàpẹẹrẹ?

      5 Ta ni ọ̀tá náà, àwọn wo sì ni àwọn èpò? Jésù sọ fún wa pé “Èṣù” ni ọ̀tá náà. Àwọn èpò sì ni “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà.” (Mát. 13:25, 38, 39) Ó ṣeé ṣe kí èpò tí Jésù lò nínú àpèjúwe rẹ̀ jẹ́ àwọn èpò kan báyìí tó máa ń ní irun lára. Kí irúgbìn onímájèlé yìí tó dàgbà, ó máa ń fara jọ àlìkámà gan-an ni. Ó bá a mu wẹ́kú láti fi àwọn afàwọ̀rajà tó pera wọn ní Kristẹni wé èpò yìí, àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ọmọ Ìjọba náà, àmọ́ tí wọn kò so ojúlówó èso! Dájúdájú, apá kan “irúgbìn” Sátánì Èṣù làwọn Kristẹni alágàbàgebè tó ń pera wọn ní ọmọlẹ́yìn Kristi yìí.—Jẹ́n. 3:15.

  • “Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò Bí Oòrùn”
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 15
    • 7. Ṣé àwọn kan lára àlìkámà di èpò? Ṣàlàyé.

      7 Jésù kò sọ pé àwọn àlìkámà máa di èpò, ohun tó sọ ni pé ọ̀tá fún àwọn èpò sí àárín àlìkámà. Torí náà, kò lo àpèjúwe yìí láti ṣàpẹẹrẹ àwọn ojúlówó Kristẹni tó kúrò nínú òtítọ́. Ńṣe ló fi ṣe àkàwé bí Sátánì á ṣe máa mọ̀ọ́mọ̀ sapá láti mú àwọn èèyàn burúkú wọlé wá, kí wọ́n lè ba ìjọ Kristẹni jẹ́. Nígbà tí Jòhánù tó gbẹ̀yìn lára àwọn àpọ́sítélì fi máa darúgbó, ìpẹ̀yìndà yìí ti fara hàn kedere.—2 Pét. 2:1-3; 1 Jòh. 2:18.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́