ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò Bí Oòrùn”
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 15
    • 5. Ta ni ọ̀tá inú àpèjúwe náà, àwọn wo sì làwọn èpò ṣàpẹẹrẹ?

      5 Ta ni ọ̀tá náà, àwọn wo sì ni àwọn èpò? Jésù sọ fún wa pé “Èṣù” ni ọ̀tá náà. Àwọn èpò sì ni “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà.” (Mát. 13:25, 38, 39) Ó ṣeé ṣe kí èpò tí Jésù lò nínú àpèjúwe rẹ̀ jẹ́ àwọn èpò kan báyìí tó máa ń ní irun lára. Kí irúgbìn onímájèlé yìí tó dàgbà, ó máa ń fara jọ àlìkámà gan-an ni. Ó bá a mu wẹ́kú láti fi àwọn afàwọ̀rajà tó pera wọn ní Kristẹni wé èpò yìí, àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ọmọ Ìjọba náà, àmọ́ tí wọn kò so ojúlówó èso! Dájúdájú, apá kan “irúgbìn” Sátánì Èṣù làwọn Kristẹni alágàbàgebè tó ń pera wọn ní ọmọlẹ́yìn Kristi yìí.—Jẹ́n. 3:15.

  • “Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò Bí Oòrùn”
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 15
    • 7. Ṣé àwọn kan lára àlìkámà di èpò? Ṣàlàyé.

      7 Jésù kò sọ pé àwọn àlìkámà máa di èpò, ohun tó sọ ni pé ọ̀tá fún àwọn èpò sí àárín àlìkámà. Torí náà, kò lo àpèjúwe yìí láti ṣàpẹẹrẹ àwọn ojúlówó Kristẹni tó kúrò nínú òtítọ́. Ńṣe ló fi ṣe àkàwé bí Sátánì á ṣe máa mọ̀ọ́mọ̀ sapá láti mú àwọn èèyàn burúkú wọlé wá, kí wọ́n lè ba ìjọ Kristẹni jẹ́. Nígbà tí Jòhánù tó gbẹ̀yìn lára àwọn àpọ́sítélì fi máa darúgbó, ìpẹ̀yìndà yìí ti fara hàn kedere.—2 Pét. 2:1-3; 1 Jòh. 2:18.

  • “Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò Bí Oòrùn”
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 15
    • Ìgbà Ìkórè Tá A Ti Ń Fojú Sọ́nà fún Tipẹ́

      10, 11. (a) Ìgbà wo ni àkókò ìkórè? (b) Báwo la ṣe ń kó àwọn àlìkámà ìṣàpẹẹrẹ wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ Jèhófà?

      10 Jésù sọ fún wa pé: “Ìkórè ni ìparí ètò àwọn nǹkan, àwọn áńgẹ́lì sì ni akárúgbìn.” (Mát. 13:39) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú yìí, iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ kan ń lọ lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ kó àwọn ọmọ Ìjọba náà jọ ká sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó dà bí èpò. Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún wa nípa èyí pé: “Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti tó fún ìdájọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run. Wàyí o, bí ó bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wa, kí ni yóò jẹ́ òpin àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere Ọlọ́run?”—1 Pét. 4:17.

      11 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, tàbí “ìparí ètò àwọn nǹkan” bẹ̀rẹ̀ tí ìdájọ́ fi bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó sọ pé àwọn jẹ́ ojúlówó Kristẹni, láti lè mọ̀ bóyá “àwọn ọmọ ìjọba náà” ni wọ́n ní tòótọ́, àbí “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà.” ‘Lákọ̀ọ́kọ́’ Bábílónì Ńlá ṣubú, “lẹ́yìn náà” a kó àwọn ọmọ Ìjọba náà pa pọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè náà. (Mát. 13:30) Àmọ́, báwo la ṣe ń kó àwọn àlìkámà ìṣàpẹẹrẹ wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ Jèhófà? Àwọn tá a kórè wọ̀nyí wà nínú ìjọ Kristẹni tá a mú pa dà bọ̀ sípò, níbi tí wọ́n ti ń rí ojú rere àti ààbò Ọlọ́run, ó sì lè jẹ́ pé wọ́n ti gba èrè wọn ní ọ̀run.

      12. Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kí ìkórè náà tó parí?

      12 Báwo ni ìdájọ́ náà ṣe pẹ́ tó? Jésù pe ìkórè náà ní “àsìkò,” èyí tó fi hàn pé ó ń bá a lọ fún àkókò gígùn kan. (Ìṣí. 14:15, 16) Ṣíṣe ìdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan lára àwọn ẹni àmì òróró á máa bá a nìṣó títí jálẹ̀ àkókò òpin. Ó di ẹ̀yìn ìgbà tí a bá fi èdìdì dì wọ́n, kó tó parí.—Ìṣí. 7:1-4.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́